Content-Length: 156861 | pFad | http://yo.wikipedia.org/wiki/Literature

Lítíréṣọ̀ - Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́ Jump to content

Lítíréṣọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Literature)
Old book bindings at the Merton College library.

Litireso tabi iṣẹ́ọnàmọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà

OHUN TÍ LÍTÍRÉṢỌ̀ JẸ́

Eléyìí náà kò ṣàì ní orírun tirẹ̀ láti inú èdè Látìn “LITERE” Èyí ni àwọn gẹ́ẹ́sì yá wọ inú èdè wọn tí wọ́n ń pè ni lete rature” Ìtumọ̀ tí a fún lítíréṣọ̀ máa ń yípadà láti ọ̀dọ̀ ẹ̀yà ènìyàn kan sí èkejì láti ìgbà dé ìgbà. Lítíréṣọ̀ kò dúró sójú kan. Babalọlá (1986), ṣàpèjúwe lítíréṣọ̀ pé:

“Àkójọpọ̀ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ní èdè kan tàbí òmíràn tó jásí ewì, ìtàn àlọ́, ìyànjú, eré onítàn, ìròyìn àti eré akọ́nilọ́gbọ́n lórí ìtàgé”

Tí a bá wo òde òní, ìtumọ̀ tí a fún lítíréṣọ̀ tún yàtọ̀, fún àpẹẹrẹ a máa ń ṣàkíyèsí ìlò èdè tí wọ́n fi kọ ìwé kan yàtọ̀ sí èyí, a tún ka lítíréṣọ̀ kùn iṣẹ́ òǹkọ̀wé alátinúdá tàbí iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìlò ojú inú gẹ́gẹ́ bí ewì, ìtàn àròkọ àti eré oníṣe. A ó sì rí i pe awẹ́ tàbí ẹ̀yà lítíréṣọ̀ tí a mẹ̀nubà wọ̀nyí kó púpọ̀ nínú ìmọ̀ ìgbé ẹ̀dá láwújọ (folklore) mọ́ ara, yálà, a kọ, ọ́ sílẹ̀, a rò ó sọ tàbí a ṣe é léré yàtọ̀ fún àwọn àkọọ́ lẹ̀ iṣẹ́ ọwọ́. Lítírésọ̀ tún jẹ́ irúfẹ́ àkọọ́lẹ̀ tó ní àbùdá ẹ̀mí gígùn, ó máa ń fi ìṣẹ̀ṣe àti àṣà àgbáríjọ àwọn èèyàn kan hàn. Àwọn míràn tó tún sọ̀rọ̀ lórí lítíréṣọ̀ ni àwọn ọmọ lẹ́yìn Mark: Àwọn Marxist (1977) yìí gbà pé:

“Scrutiny of the literature could not be realize without the society”

Èyí ni pé:

“Lítíréṣọ̀ kò lè ṣe é dá yẹ̀wò láìwo àwùjọ tí a kọ ọ́ fún”

Kí òǹkọ̀wé kan tó lè se iṣẹ́ rẹ̀ ní àṣeyanjú, irúfẹ́ oǹkọ̀wé náà gbọ́dọ̀ ni àtinúdá àtinúdá yìí pẹ̀lú ohun gan-an tí ó ń ṣelẹ̀ láwùjọ ni yóò wá sọ di ọ̀kan nínú iṣẹ́ rẹ̀. Lara àwọn tí ó ṣiṣẹ́ lórí ìlànà Marx yìí ni: Trosky ara Russia, Lucas àti Goldmann. Daviguand (1960) ni tíọ́rì sọ pé

“Literature enumerate the future thought of an individual (Human being)

Èyí ni pé:

“Lítíréṣọ̀ wà fún láti máa so èrò ọkàn ènìyàn jáde nípa ọjọ́ iwájú”

Nípa yíyẹ lítíréṣọ̀ wò, à ní láti wo ẹ̀hun ìpìlẹ̀ ìtumọ̀, èyí ni wíwo gbogbo nǹkan tí ó wà láwùjọ yẹn olápapọ̀ láì dá ọ̀kan sí.











ApplySandwichStrip

pFad - (p)hone/(F)rame/(a)nonymizer/(d)eclutterfier!      Saves Data!


--- a PPN by Garber Painting Akron. With Image Size Reduction included!

Fetched URL: http://yo.wikipedia.org/wiki/Literature

Alternative Proxies:

Alternative Proxy

pFad Proxy

pFad v3 Proxy

pFad v4 Proxy