Content-Length: 124191 | pFad | https://yo.wikipedia.org/wiki/Ascariasis

Ascariasis - Wikipedia, ìwé-ìmọ̀ ọ̀fẹ́ Jump to content

Ascariasis

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ascariasis
AscariasisAscaris lumbricoides
AscariasisAscaris lumbricoides
Ascaris lumbricoides
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10B77. B77.
ICD/CIM-9127.0 127.0
OMIM604291
DiseasesDB934
MedlinePlus000628

Ascariasis jẹ́ àrùn tí kòkòrò ajọ̀fẹ́ tí a npé ní aràn alára rógódó Ascaris lumbricoides nṣe òkùnfà rẹ̀.[1] Àkóràn àrùn náà kò ní ààmì àìsàn kankan lára marundinlaadọrun nínú ọgọrun (85%) àwọn ènìyàn tó ti ní àrùn náà, pàápàá bí iye àwọn aràn náà bá kèrè.[1] Àwọn ààmì àìsàn a má a pọ̀ síi pẹ̀lú iye aràn tó wà lára, lára irú àwọn ààmì bẹ́ẹ̀ sì ni àìlèmíkanlẹ̀ àti ibà ní ìbẹ̀rẹ̀ àìsàn náà.[1] Àwọn ààmì àìsàn bíi inú wíwú, inú rírun àti ìgbẹ́ gbuuru lè tẹ̀lé èyí.[1] Àwọn ọmọdé ni ó má a nsábà ní àkóràn àrùn náà, láàárín àwọn ọmọdé bẹ́ẹ̀, àkóràn àrùn náà tún lè ṣe òkùnfa àìlẹ́ranlára, àìtó èròjà oúnjẹ lára àti àwọn ìṣòro nípa ẹ̀kọ́-kíkọ́.[1][2][3]

Àkóràn àrùn náà a má a wáyé nípasẹ̀ jíjẹ oúnjẹ tàbí mímu omi tí ẹyin aràn tí à npè ní Ascaris náà, èyítí ó ti inú ìgbọ̀nsẹ̀ jáde wá, bá ti kó sí, tí ó sì ti sọ di àìmọ́.[2] À ó pa àwọn ẹyin náà nínú ìfun, àwọn aràn náà a sì gbẹ́ ihò sínú ògiri ikùn ènìyàn, wọn a sì gba ibẹ̀ lọ sínú àwọn ẹ̀dọ̀fóró nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀.[2] Níbẹ̀ wọn yóò wọ inú àwọn àpò atẹ́gùn inú ẹ̀dọ̀fóró, wọn yóò sì ṣàn lọ sókè nínú ọ̀nà-ọ̀fun, níbití a ó ti wú wọn jáde bí ikọ́, tí a ó sì gbé wọn mì.[2] Àwọn ìdin náà yóò sì gba inú ikùn kọjá fún ìgbà kejì sínú ìfun níbití wọn yóò ti dàgbà sí aràn nlá.[2]

Ìdènà àrùn náà níí ṣe pẹ̀lú ìmọ́tótó, èyítí ó kan mímú ìlọsíwájú bá níní ànfàní sí ilé-ìyàgbẹ́ àti dída ìgbẹ́ nù ní ọ̀nà tí ó tọ́.[1][4] Ọwọ́-fífọ̀ pẹ̀lú ọṣẹ farahàn bí ààbò tó péye.[5] Ní àwọn agbègbè ibití iye ènìyàn tó ju méjìlélógún nínú ọgọrun (20%) lọ ti ní àkóràn àrùn náà, a dámọ̀ràn pé kí a ṣe ìtọ́jú gbogbo ènìyàn láti ìgbà dé ìgbà ní tẹ̀lé-n-tẹ̀lé.[1] Wíwáyé àrùn náà lára ẹnití ó ti níi rí jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀.[2][6] Kò sí àjẹsára.[2] Àwọn ìtọ́jú tí Àjọ Ìlera fún Àgbáyé dámọ̀ràn ni àwọn egbògi bíi albendazole, mebendazole, levamisole tàbí pyrantel pamoate.[2] Àwọn egbògi mìíràn tó tún má a nṣiṣẹ́ ni tribendimidine àti nitazoxanide.[2]

<!—Àtànká àti Ìṣàkóso àtànká àrùn --> Iye àwọn ènìyàn tó tó bílíọ̀nù 0.8 sí 1.2 káàkiri àgbáyé ni ó ní àrùn ascariasis, tí àwọn àwùjọ tó sì ní àrùn náà púpọ̀ jùlọ sì jẹ́ àwọn ará Gúsù Sahara Afirika, Amẹrika Latini, àti Eṣia.[1][7][8] Èyí mú kí àrùn ascariasis jẹ́ ẹ̀yà àkóràn aràn ajọ̀fẹ́ nípasẹ̀ iyẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ tó wọ́pọ̀ júlọ.[7] Ní ọdún 2010, ó ṣe òkùnfà ikú àwọn ènìyàn tó tó 2,700, èyítí ó wálẹ̀ láti ènìyàn 3,400 tó kú ní ọdún 1990.[9] Oríṣi aràn Ascaris mìíràn a má a ran àwọn ẹlẹ́dẹ̀.[1]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 1.6 1.7 1.8 Dold, C; Holland, CV (Jul 2011). "Ascaris and ascariasis.". Microbes and infection / Institut Pasteur 13 (7): 632–7. doi:10.1016/j.micinf.2010.09.012. PMID 20934531. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 2.6 2.7 2.8 Hagel, I; Giusti, T (Oct 2010). "Ascaris lumbricoides: an overview of therapeutic targets.". Infectious disorders drug targets 10 (5): 349–67. doi:10.2174/187152610793180876. PMID 20701574. 
  3. "Soil-transmitted helminth infections Fact sheet N°366". World Health Organization. June 2013. 
  4. Ziegelbauer, K; Speich, B; Mäusezahl, D; Bos, R; Keiser, J; Utzinger, J (Jan 2012). "Effect of sanitation on soil-transmitted helminth infection: systematic review and meta-analysis.". PLoS medicine 9 (1): e1001162. doi:10.1371/journal.pmed.1001162. PMC 3265535. PMID 22291577. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3265535. 
  5. Fung, IC; Cairncross, S (Mar 2009). "Ascariasis and handwashing.". Transactions of the Royal Society of Tropical Medicine and Hygiene 103 (3): 215–22. doi:10.1016/j.trstmh.2008.08.003. PMID 18789465. 
  6. Jia, TW; Melville, S; Utzinger, J; King, CH; Zhou, XN (2012). "Soil-transmitted helminth reinfection after drug treatment: a systematic review and meta-analysis.". PLoS neglected tropical diseases 6 (5): e1621. doi:10.1371/journal.pntd.0001621. PMC 3348161. PMID 22590656. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3348161. 
  7. 7.0 7.1 Keiser, J; Utzinger, J (2010). "The drugs we have and the drugs we need against major helminth infections.". Advances in parasitology 73: 197–230. doi:10.1016/s0065-308x(10)73008-6. PMID 20627144. 
  8. Fenwick, A (Mar 2012). "The global burden of neglected tropical diseases.". Public health 126 (3): 233–6. doi:10.1016/j.puhe.2011.11.015. PMID 22325616. 
  9. Lozano, R (Dec 15, 2012). "Global and regional mortality from 235 causes of death for 20 age groups in 1990 and 2010: a systematic analysis for the Global Burden of Disease Study 2010.". Lancet 380 (9859): 2095–128. doi:10.1016/S0140-6736(12)61728-0. PMID 23245604. 








ApplySandwichStrip

pFad - (p)hone/(F)rame/(a)nonymizer/(d)eclutterfier!      Saves Data!


--- a PPN by Garber Painting Akron. With Image Size Reduction included!

Fetched URL: https://yo.wikipedia.org/wiki/Ascariasis

Alternative Proxies:

Alternative Proxy

pFad Proxy

pFad v3 Proxy

pFad v4 Proxy