SHC

Download as doc, pdf, or txt
Download as doc, pdf, or txt
You are on page 1of 58
At a glance
Powered by AI
The document discusses various herbal remedies and treatments for different health conditions.

Treatments mentioned for headaches include praying to certain deities, drinking herbal concoctions, and applying herbs to the head.

Causes of excessive vaginal discharge mentioned include poor hygiene, hormonal imbalances, and infections.

IJUBA

(DEDICATION)

IBA AKODA! IBA ASEDA! IBA AMOLESE, IBA AMONOSE TAARA DEFE,IBA ODE

SAPOYORO,IBA ARONIMAJA SAPO YOOGUN,IBA EJO KO KOMO YOOOYOOO LO

JEUN,IBA ABALORI IROKO MAYE,IBA ONIBANTE PELEJA TI NBANIJA LAIFOWO

KANNI,IBA BABAMI,IBA YEYEMI,IBA TOTOFUNNNN,BI ABAPERI AKONI AFI FILA

NALE! CHIEF SOSAN SULAIMAN IBARE OOOO,ADANISE NI NWUN NI,IBA KO

GBODO WUN OMO ENIYAN.

MO TUN WA JUBA ODUA LALE IFE,IBA OLUBIKIN,IBA OSANYIN-

BIKIN,AJAGUNMALE....AWO NLA LODE ORUN IBARE OOO,IBA GBOGBO EGBE

ONISEGUN IBILE NI GBOGBO AGBAYE,IBA GBOGBO EGBE ONISEGUN LORI ERO

ALATAGBA(INTERNET HERBAL MEDICINE PRACTITIONAL GROUPS).


IDUPE:

OPE PATAKI LOWO OLOHUN TO BAWA SE "IWE OOGUN IWOSAN ARUN AYERAYE TI

ANPENI SOSAN HERBAL CENTER (S.H.C BIBLE) NI ASEYORI, MO TUN DUPE LOWO

GBOGBO AWON OJOGBON TI WON KO JE KI IBUDO NLA (S.H.C) GBE FUN

ONIRUURU OGUN IWOSAN, SIWAJU SII.

MOTUN DUPE LOWO GBOGBO ELETO (S.H.C ADMIN) ATI GBOGBO OMO

EGBE PATAPATA TI AJIJO SOWOPO GBE IWE YII JADE,MO NFI AKOKO YII BE

OLOHUN WIPE AISAN KONIFI ARA ENIKOOKAN WA SE IBUGBE OOOOO,MOTUN WA

NBE OLOHUN FUN ASE WIBE-JEBE LORI AWON OGUN INU IWE YII WIPE GBOGBO

AISAN TI E BA TI FI TOJU,AISAN NAA KONI GBERI MO LAELAE. (AMIN).


ABOUT THE AUTHOR:

EMI SOSAN NURUDEEN JE OMO AGBEGBE TI WON NPE NI AGO OBA NI ILU

ABEOKUTA,BABA TO BIMI LOMO NI WON NPE NI CHIEF SOSAN SULAIMAN

(JAGUNMOLU GBOGBO ILU OBA,APENA ONISEGUN TILE-TOKO).

SE KI AMA PARO AJOGUNBA NI ISE ISEGUN IBILE JE FUN IDILE WA,ISE TI

MOSI GBONJU BA LOWO BABA MI NIYEN SUGBON MODUPE WIPE EMI NAA TUN TE

SIWAJU LORI ISE IWADI NIPA OGUN IBILE OPOLOPO ASIRI NI MO TUN BA PADE

LODO AWON ORE MI TI AJO NSARE KI ASA ATI ISESE OMO YORUBA MA LE PARE

LORI ILE AYE,NINU AWON IGBIYANJU NAA LOBI IWE TI MOTE JADE TI ANPE NI

S.H.C BIBLE SOLUTION TO ALL HEALTH CHALLENGES .NITORINAA TI ABARI

NKAN TOKU DIE KAATO NIPA IWE YII NI AFIKUN TABI AYOKURO E PEWA SI AWON

NUMBER YII

DR. SOSAN NURUDEEN CONTACTS

1. 08060546348. (MTN)

2. 08076265662. (GLO).
MIMO RIRI ARA ENI

S.H.C (SOSAN HERBAL CENTRE) nfi akoko yii dupe pelu kiki awon
OJOGBON ti won bawa bere ILE-IWOSAN yii pelu awon ogun iwosan
TESTED OKAY lorisirisi awon naa ni:

1. DR. agbara
2. Adewale Scott
3. DR. Muyiwa T.O.Onibiyo
4. Lateef Ganiu
5. Fatai Idris
6. Tobi Abioye Campus
7. Shittu Olohunosebi
8. Taiwo Kehinde
9. Abdul Fatai Ayinla
10. Awwal Olamijuwon
11. DR. Abul Fathi Balogun
12. Akamu Kazeem
13. DR. Adetoyi Adekunle
14. Akinde Timothew
15. DR. Monisola Oguntoye
16. DR. Alao Temitope
17. DR. Ibrahim Junaid
18. Prince DR. Mattew
19. DR. Wasiu Olohunosebi (ABU)
20. DR. MRS. Adeleifa Ajiyonotun
21. DR. Olasunkanmi Elijah
22. DR. Iyanda Jamiu Karamo
23. DR. Ayomide Saidat
24. DR ABEJIDE BABAGBEMI
25. DR ADEBAYO KAYODE TESLEEM
26. BABALAWO AJAYI OLADELE
27. DELE EMMANUEL
28. WOOLI OBA EMI
29. ATI gbogbo eyin ti ako le ranti daruko wipe OLOHUN YIO SE ISE TIYIN
NAA LASEPE O.
IDANILEKO RANPE NIPA AWON TI ONFA TI OYUN FI NBAJE LARA ALABOYUN.

LATI ENU BABA WA


DR. ABEJIDE BABAGBEMI

AWON NKAN TI O NFA TI OYUN FI N BAJE LARA ALABOYUN.

Awon nkan ti o maa n boyun je lara alaboyun ni awon nkan wonyi:

-- Lilo ogun lai gba ase lodo dokita

---Mimu oti lile tabi igbo tabi siga


---Ise sise ti o ni agbara

-- Igbona okan ati

---Aisan inu ara eleyi gba akiyesi pupo eyi ti agbodo fara bale lati ko eko re. Awon aisan wonyi
ni:

1. Eje riru. (Hypertension)

2. Arun ito suga. (Diabetes)

3. Yikiyiki. (German Measles)

4. Ako ifibe. (Pelvic Inflamatory disease)

5. Aran Aginisa. (Helminthiasis)

6. Ki omi o poju ninu ile omo. (Polyhidraminus)

7. Ki onubi omo ki o ma duro dede si ibi ti oye. (Placenta privea)

8. Kokoro inu ile omo. (Endometritis)

9. Arun warapa oyun. (Eclampsia)

10. Iju ninu ile omo. (Fibromyomata)

Awon gbogbo nkan wonyi ni o le fa ki oyun baje lara obirin ti ako ba Mun oju to.
BI A TI SE LE DEKUN OYUN BIBAJE (PREVENTION)

Ani lati se awon akiyesi pataki won yi lati dena oyun bibaje lara awon alaboyun wa:

 -ki a sora fun ogun lilo lona aito


 ki alaboyun sora fun mimun oti lile tabi igbotabi siga ati ogun oloro
gbogbo(cocaine,heroin,etc)
 Alaboyun ni lati se ise niwon tuwonsi lai pa omo inu re lara
 O ye ki alaboyun o fi okan ara re bale ninu oyun lai si ifoya
 Alaboyun ni lati sora fun ija ati ijangbon
 Jije ounje ti oni eroja asara lore se pataki ninu oyun
 Paripari re ni wipe ki awon alaboyun ma lo fun ayewo lorekore ni ile iwosan lati mo bi
ara won seri (Antenatal)
 Mo gbadura fun gbogbo awon ti won diwo dise sinu pe won a ruu re won a soo re o Afon
agbo ki o to wo o nitori boro ni ejo n bofo,kete bai ni adiye n boko eyin Lase ti Edua.
Ese adupe fun itetileko.
BY DR. ABEJIDE BABAGBEMI.
(1) OGUN ATOSI/GONORRHEA /STD)
(a) egunsi bara, epa ikun, alubosa funfun, kafura, a o be egunsi yen, a o ko egunsi inu re kuro, a o be
epa ikun yen na, a o ge wewe, a o wa fi kafura tele igo kan, a o wa ko bara yen PELU epa ikun yen
ati alubosa funfun yen si, a o wa da oti ibile si, a o ma mu nigasi kokan láró láró.

(b)OGUN ATOSI
KANFO ROGODO KAN A LO A PO MO OORI LOCAL BUTTER,A DI SINU NKAN TAFEFE O
NI TI FESI,A MA MU OGI GBIGBONA.

(c) OGUN ATOSI ATI ARA WIWU:-


ao wa ewe ojoyun(esin funfun) odindi atare kan,ao jo papo ao mafi oti sekete lo ebu yen.

(d) OGUN ATOSI


Baara egusi nla kan,epa ikun, baaka,ao gewon sinu ike 2ltr,ao lora tetraxyclin capsule,ao si ra
chlorophenicol capsule ao pa gbogbo re papo sinu ike yen ao ro omi khal tufa si, ao mamu leyin ojo
keta.

(e) OGUN ATOSI OLOYUN


GBEGI Ao tu tiditidi bobase wuwa ,ao gbon yerupe idire nun ao wa gbo ti yio ki ao ma mun ,koda
gan elero sinun ike olomo ri kagbe ranse siyan nilu okere.

(f) OGUN ATOSI EGBE


Ao bara kan ao sun ninu ina ao ko gbogbo egusi inu re danu ao ge bara ye wewe sinu ike funfun
5litres ao ge egbo ogbolo tutu si wewe ao dasi ao ge epaikun si wewe ao dasi ao wa da emu gidi le lori
ao fi sile fun ojo meta 3days ao ma mu diedie laro ati lale leyin ojo keta opari ó dájú.

(g) AGUNMU ATOSI


Ao wa orogbo gbigbe iyekiye ewe akerejupon egbo ekija egbo logbokiyan ao gun gbogbo re papo ao
mofi eko gbigbona lo laro kato jeun tabi kafi foko tutu mu opari

(h) OSE ATOSI:-


Egbo oja ikoko,egbo gbogbonise,alubosa elewe,ora adie,ao gun awon egbo yen papo,ao po lose dudu
tabi ose aganyin, ao po ora adie namo, ao ma fire. AKIYESI:-ti abanfi ose yiwe ti atosi basiwalarawa
arawa yio mayo sugbon ti atosi yi batisan tan arawa koniyomo.

(i) ATOSI:
Odindi epa ikun, odindi bara kan, ako kanhun, baka die, a o fi emu da lagbo, a o gbepamo fun ojo
meta, a o ma yo mu lehin ojo keta.

(j) APARUN ATOSI TABI TI NKAN FUNFUN NYO LABE OBINRIN:


A o be bara nla kan sinu ike 4 litres,eku asin gbugbe kan a o ya wewe sinu re,a o ge epakun,egbo
oruwo,egbo sapo,egbo asunrun oyinbo ati ibile sinu re,a o wa da opolopo oronro maalu ati ogogoro
papo sinu re a o de pa fun ose kan,A o maa mu ni ilaji cup ni ilaji kutukutu siwaju ounje ati ti aba fe
sun fun ojo marun leralera lehin ekan lojo ketaketa.

(k) (OGUN ATOSI)


EWE BOTUJE F.F. EGBO BOTUJE. EGBO ERUJU. BARA KAN. AOBE EPO ARARE
DANU.PELU AWON OMO INURE. AOFI BAKA SI PELU TEYO DIE. ATI EWE PARISA. EPO
AYE.EPO AKOMU. AOFI OMI OSAN WEWE RE NI AGBO TUTU. AO MA MUN NI GAS
Kokan.

(l) OGUN ATOSI ISU ABIRISOKO


AO GE SI KEKEKE OGEDE AGBAGBA TI KO PON AO GE SI KEKEKE AO KO SINU IKOKO
AO BU OMI SI AO DE PA FUN OJO META AO MA YO MU LARO Lale.

(m) ATOSI GONOREA


Egusi bara toba gbo dada, aowo omo inure danu aoge si kekeke sinu omi osan wewe,ninu igo kan
aofi kahun bilala die si lati aro ojokeji otidi mimun cup kekere meji laro kato jeun meji lale leyin
oúnjẹ.

(n) OSISE FUN ORU INU TI OTUN SISE ATOSi.


Odidi orogbo kan odidi atare kan eeru Alamo fofo okun abo ogede wewe ata pupa ao gun gbogbo
re ni agunmu eko gbigbona ni ao mafi mu ó dájú.

{o} OGUN YINSE ISEFUN IJU TABI ATOSI EGBE.


OPOLOPO ENUKOPIRE ESO LARAPUPA AKOKANWUN OSE DUDU TOPO AOJOPO
AOMAFI OTI LO.
(p) OGUN ATOSI
AKUKO ADIYE KAN.AOPA.AOGBA IDI REKO ORO AGOGO ATI ENUOPIRE ODINDI SINI
NU AOWAGBE SINU AGBADA AOJO AOLO AO MAFI FO EKOMU.

(q) OGUN ATOSI ELEJE


Asunwon oyinbo pupo,egusi due,ati epo,iru,iyo obe,ao wa fi pepe efon re awon ewew yen,ao wa se ni
obe fun eni yen je pelu eja aroni kan,pelu ogo olohun yio ya gbogbo re danu.

(r) OGUN ATOSI ELEJE


Egbo ako ibepe enu opire, bara, ako kaun, odidi atare, aojo po ao fi oti tabi omi osan wewe lo.

(s) OGUN ATOSI ELEJE


egbo ako ibepe enu opire, bara, ako kaun, odidi atare, aojo po ao fi oti tabi omi osan wewe lo.

(t) OGUN ATOSI ELEJE


Tagiri kan,bara kan,opon oyinbo kan,kanwun bilala,ewe botuje pupa ati funfun,,a o fi omidun da
lagbo tutu a o ma mu. By Sosan

(u) OGUN ATOSI TODAJU


EWE ABO KOPO DADA,ALUBOSA ONISU,ERU ALAMO,AKOKAUN,IYO OBE,AO GUN
PAPO,KI O KUNNA DADA,AO MA FI MU EKO GBIGBO NA LAROLARO.

(v) OGUN ATOSI EGBE:


Idandanran tiro, sugar onikoro,ako kanwun a o lo won papo a o maa fi mu eko gbigbona.

(w) OGUN ATOSI TI OMA NSARE PA ATOSI:


A o tu CHLORAPHENICOL SACHET KAN SINU GLASS CUP,A O TU PEAK MILK HOLLAND
KAN SINU RE A O FI SIBI RO PAPO DARADARA ENI NAA YIO SARE GBEMU.PELU OGO
OLOHUN TI ENI YIO BATO LEHIN OGUN YI KO NITO OYUN MO.KI EWA SE AGBO YII
FUN:
Bara,KAN,EGBO ORUWO,EPAKUN4,BAKA5,EGBO SAWORO,OMIDUN SE JINNA YI MAA
MU LARO LALE.

(x) OGUN ATOSI:


EWE ASUNRUN OYINBO,EGBO ASUNRUN IBILE,A O GE BARA KAN SINU RE,KANHUN
BILALA,A O SE WON PAPO A O MA MU NI CUP KOOKAN LOJUMO. Nurudeen Sosan

(y) OGUN ATOSI ELEJE


A O FI OMI GBO EWE AGO IGUN,ORUBU EFUN KAN,A O LO SINU RE,ENI NAA YIO MAA
MU NIGBAGBOGBO.

(z) . IWOSAN ATOSI OLOJO PIPE.


AO TOJU AGBO JIJE (Ccoconut). MEJI, IREPE IKO, ( eso iko).MEFA, OWO EYO TI KO LUJU
MEWA, AO DA OMI INU AGBON YAN NU, AO GUN NINU ODO PEPE, AO GUN IREPE IKO
NAA BEE, AO WA KOO GBGBO RE SINU APE, AO JOO PELU ODIDI ATARE KAN, AO LOO
KUN NA.
Lilore:- AO MA FI MU EKO GBIGBO NA LAARO LAARO, SIBI IJEUN KAN TITO.

2. OGUN AROMOLEGUN (ROMATICISM)

(a) OGUN AROMOLEGUN :


egun Aja ewe afeloru atare odidi kan ao Jo po lilo kuna ki a bu sibi MEJI sinu oti mimu gas cup kan
aro ati ale koni re wa ó.

(b) OGUN AROMOLEGUN


OKO OGEDE WEWE, IGBA AYA ALABAHUN, AKO KONHUN OSE DUDU JIJO AO Mala.

(c) Awoka Tabi Aromolegun


Obi Abata merin (Wonderful Kola4), Atale merin (Ginger 4), Atare odidi meji,Iyere,Ewe
efirin,Orogbo Marun... Ao lo gbogbo re papo... Ao re pelu omi osan wewe... Sibi meji ni aro ati ale....

(d) Ogun arunmolegun.


Omo aja kan ao pa ao ro eje re sinu abo kan, ao ni ki eni ti arunmolegun nda lamu kio gbemu lasiko
ti aisan na banse kotun gburo re mo lailai.

(e) OGUN AWOKA TABI ARUNMOLEGUN


OBI ABATA MERIN,ATA ILE MERIN,ATARE MEJI,IYERE,EWE EFINRIN,OROGBO
MARUN,AO LO GBOGBO RE PAPO,AO DA SINU OMI OSAN WEWE,AO MA LO SIBI MEJI
NI ARO ATI Alẹ́.

(f) OGUN ARUNMOLEGUN


Egungun Iha Eran Agbonrin(igala) A O Jo Pelu Odidi Atare Kan. Gbenren Si Orikerike Ara.

(g) ERO ARUNMOLEGUN:-


EGUNGUN ESE AKO, EGUNGUN INAKI, EGUNGUN AJA, A O LO PO TABI KI A JO WON PO,
A O PO MOSE DUDU, A O FI MAA PARA FUN ONITOHUN. OGUN ORU INU:- IGBIN NLA
KAN, ILE ALADIN, ODINDI ATARE KAN, A O JO PO, A O MAA FI FOKO MUn.
(h) OGUN FUN ARUNMOLEGUN
Igo oyin kan aoda sori ina tiobatiun so kutuputu aoda Iru Woro si, aoropo dada aowa sese sokale
aoda Sinu Igo nla kan tiobati tutu tan, odi Mimu nisibi kan laro ati lale...

(i) Aromolegun;
ao fi 2 ltrs keg omi osan wewe gbo ewe guava to po die ao see. Ao maa je carrot laaro kutukutu
ojoojumo ao si mu eto yi lee lori.

(j) OGUN AROMOLEGUN(romanticism)


Imi esin,egbo isepe agbe,egbo kakansela,fulufulu inu suku agbado,ao gun papo ni agunmun,ao mafi
mun eko gbigbonan tiko ki,oparun ni ao fima famu,ao gbodo gbemu,ao si gbodo fi sibi mu,.

(h) AWOKA ABI AROMOLEGUN(ABBL).


TANGIRI ABE ISURE-IMIN OJO PUPA-KANFO-AIDAN-ERU AWONKA-ALUBOSA ELEWE-
AGUN PAPO MOSE DUDU-AKO SINU IGBA OLOMORI-AGBE SINU ILE-KANHINKANHIN
TABATI NLO NA LAMA LO TITI AFILO OSE NA TAN-AKO IGBA NA ATI KANHINKANHIN
NA SONU- 2-AGBO TAMA MU TABA NWE OSE YI RE- ERELE IBEPE AKO-AO SE LORI INA-
TOBA HO DADA-AMA FI EEGUN EYE AKOO FAMU-NINU ABO TABI TOMBILA.
3. OGUN AFATO (SPERM BOOSTER)
BOYA O KII LE BA OBINRIN SERE LE MEJI TABI JUBELO.....

(a) ewe ojoyun, egbo ogbolo, egbo sagere tutu,ogede agbagba dudu, ao ao ge won wewe, ao sa
mererin gbe, ao gun LAGUNMU ao lo sugar elekoro mo, ao ma fi omi lo lale ti abafe sun, omi
kiitan nidi akere niyen.

(b) bara kan.epa iku,egbo ogbolo.paran pupa.egbo gbaingboin..a o ge keke sinu ike eva kan.a o
da omi si.tia ba feran otin ale fi ki bakana.a o be bara yen a o tun ko egusi inu re kuro .mimu
leyi ojo keta.ema je ki egbo ogbolo ju idakan ninu oni 100 tia ba ra.

(c) EGBO OPE,EGBO AGBON,EGBO OGBOLO.....AOGE KEKE SINU IKE EVA NLA,AOFI
MILK TABI OMI KI, IGBA TI OBA WUWA LAOTO SO KALE OKE TI ABAGUN.....IYAWO
RE MA SA JADE NI.

(d)Ibepe dudu ao be epo eyinre danu,ao re were si inu igo,egbo Ogbolo ao re si,ao fi suga die
si,ao bu omi tutu ti oba mo si,ao ma yo mun diedie lojojumo.
(e)ogede agbagba dudu kan.aobo epo arare aora epo ogbolo aogeke keke.sinu ikekan aoda
ogede nye naasi.aoge ohunaa kekeke aodasi aowabu ominsi aogbepamon fun 7 hours lehin 7
hours (wákàtí meje) otidi lilo niye o.eniti kobani iyawo nile komalo.aowada epo ogede nye nun.

(f) ENI TO BA FE SE ISE YI YO TI KOKO LO OGUN JEDIJEDI TI YO TI FO GBOGBO


IDOTI INU RE DANU KI O TO LO OGUN YI KI O LE BA GBADUN RE DAADAA.
AO WA EGBO ASOFEYEJE ATI EGBO OGBOLO, AO GE AWON EGBO YEN KEKEKE,
AO KI SINU IGO PELU OMI TUTU. AO MA MU LEYIN OJO KETA. EO YIN OLOHUN
LOGO.

(g) Aowa ewe ajeobale tutu aogbo pelu omi aomun aoma sebe fun osekan tio gbodo ja laro lale,
tio ba pari eleyi walowa egbo ogbolo tabi afato aoge kekeke sinu oyin igan mimu laro lale fun
ose kan. Toba lo agbo mejeji yi tan boya kolo feyawo elekeji tori komon ba pa iyawore, ikilo lori
agbo yi nipe wajin na si gbogbo un tiwon fi sugar se tabi nkan toba dun ju ikeji nipe aogbodo
sunmon obinrin ti anba lo iseyi lowo.

(h) -Egbo ogbolo tutu ao gun ao san mo eyin omori igba ao sasi oorun tiogbe,ao lo ao maafimu
eko.

(i) OROGBO BI EYO MEJI, ATARE ODIDI KAN, IKUNMU APADO(ao ri ra lodo awon elewe
omo). OGEDE AGBA TO PON, EKUKU JIJE GBIGBE, AO GUN PAPO, AO SAA GBE, AO
TUN GUN KUNNA, Lilore:- OKUNRIN NAA YO MA FI MU OGI GBIGBONA SIBI KAN
ABO LAO MAA BU SII OGI LARO LARO.

(j) Eso igi atori, ojele ewe obi, ao lo po, ao sa gbe daada, ao wa da sinu oyin igan gidi, ao maa la
die-die laro ati lale..
4. OGUN IDAKOLE
(a) Okuta ako to funfun daadaa, ao loo kuna bii elubo, Iwo maalu to gun, tosi tobi daadaa, ao
ha idoti ara re kuro pelu ada tabi obe, ao wa ha eyin re sile daadaa pelu ada, ao gun ninu odo
onirin ti yoo kuna daadaa. Ao bu awon nnkan ti a lo yii ni odiwon kannaa, ao dawon papo
daadaa.

LiLO RE : Ao koko fi mun eko gbigbiona laaro kutu fun ojo meje leralera, leyinaa, a o maa loo
leekookan.

(b) Ako igbin 1,Aojopomo Odindi atare kan. Ao lọ kunna, aowalo Eku Pete tiyiokunna Dada
topo die, aoda papo ma eyiti ajo.
Aomaafi fo eko tutu mu, abiki amafi oyin laa.

Note:-Eku Pete owa Ni odo awan tiwanta èwedu.

(c) Ako okuta,esan ekuro,korofo eyin adie ,sugar onikoro ao lo kuna dada ao ma fi mu eko
gbígbóná.

(d) IDAKOLE,Ori oka kan tio lase lenu,ao lo kunan,a lo ako okuta kunan bakan naa,a o wa lo
papo dada,a o ku pelu ajo, a da sinu ike kan ao ma fi omi tutu lo ni aaro kutukutu,odaju gan o.

(e) ESO BONNI TOPO DIE-OROGBO 3-ODIDI ATARE 3-IRU-IYERE-ALUBOSA ELEWE-


KANHUNBILALA DIE-ERELE EWE IPIN-AGUN PAPO-AO JO-AMA FIMU EKO
GBIGBONA.

(f) Ao wa egusi baara kan, ao wa ge sinu ike eva water, ao wa da minerals fanta le lori. Ao maa
mu ni lojojumo.
Nb: tio ba fe gba match bu die kio mu.

(g) AGBO YI WAFUN AWON TI NKAN OMO KUNRIN WONTOBI TELE TOWA SUNKI
TIKO TOBI MO, TABI IDAKOLE,ENI TOBA NIFE SI NA LELO
Idoti abe loma nfa nkan bayi, toje wipe nkan nkan omokunrin awa shrink papo tiko ni tobi mo.

Aolowa pineapple kan, kahun gidi die, bara nla kan, epa ikun
SISE RE- ao gun kahun die yen ao ko si ibi kan, Ao fo bara yen toma mo daada ao wa ke
kekeke sinu ikoko ao tun wa e pineapple yen kekeke si lori, ao ko epa ikun le naa, ao wa da
kahun ti agun si ao wa bu omi si ao de ao se ti yio jina daada, toba ti jina yio dudu, ao wa sokale
kio tutu...ao ma mu ni tombila kookan lojojuma.

APERE TI AO MARI:- yio ma koyan ninu gaan, yio si wa ma ko iditi towa labe, ti aba loyagbe
yio ma run eo sima ri idoti ti eo ya jáde.

(h) Egbo akerejupon, egbo akoogun, egbo owuru, epo aganho, ao ge kekeke sinu igo, ao fi
ogogoro kii lagbo, mimu ni gasi kokan leyin ojo kẹta.

(i) Egbo Asisa; ege niwon mejila, Oko Òbúkọ kan,Orogbo kan, Ata jije dudu ekun owó kan,
Kahun Bilala niwon, Egbo Osunsun;ege niwon mejila, Ataare kan, ao gùn won po ni agunmun,
ao ro sinu igo, ao ro irin ti yio kanle ninu igo na ti yio si di
lenu, ohun ni ao ma fi de igo na...ao má fi foko mun leralera.

(j) ao wa odindi alubosa funfun meje,ao ge si wewe,ao wa se pelu omi,ti o ba jinna,ao da omi re
nu,ao wa fun omi ara alubosa ye sinu koopu ki e sin da oyin gidi die si,\ LILORE:sibi ijeun meji
ni aro ati ni ale fun ose meji.

(5) OGUN IJU (FABROID)


(a) aban eyin (eyin toso lori iyare tikotigbo) ibepe dudu oro agogo atare meje ao jo po a lo
adasinu adi amamu ni sibikan laro losan lale toba mafimu larin ose kan oma bi ijuna tori aburu
po ninu kiwan se ise abe fun eni toni oyun iju iman fa awari funwan ni olohun aje kobara mu''.

(b) OOGUN OYUN IJU- FIBROID


Isu alubosa were, Kanhun Bilala, Odidi ataare mẹta, Irú, Aidan, Ewe Ominsinminsin, Baaka
die, A o gun gbogbo re papo ti yoo kuna daadaa, a o daa sinu omi orombo were, mimu ni gaasi
kan soso ni aaro ki a to jeun. Obinrin naa yoo loo fun ose meta lojoojumo leralera.

Lehinaa, ki o lo ya scan, pelu ogo Olorun, iju naa yoo ti poora.

AKIYESI PATAKI: Kii se gbogbo igba ni scan yiya maa n ri nnkan to nse eeeyan pato ninu. Bi
won ba ta eniyan lofa, scan le gbe orisirisi esi jade- o le so wipe eniyen ni arun

HIV/AIDS tabi fibroid- ise awon agba ni. Fun idi eyi, a ni lati se ayewo daadaa ki a lo mo boya
iju ni tooto. Bi won ba se ise abe fun obinrin miran ti scan so wi pe oni oyun iju, won ko ni ba
nnkakan nibe. There is need to be 100% sure that it truly fibroid through the
instrumentalisation of medical and spiritual findings.

(c) Epo igi amuyan, eso bara, ewe akoko, ewe ekaja, iyo, a o se lagbo mímú.

(d) olu iju, eso Lara funfun, a da sinu adin eyan Lila.

(e) Egbo wowo atare meji, imi ojo, taba gidi, a o lowo pon sinu omi orombo were, tabi oti mimu
ni gaasi kokan laro.

(f) Eja aro ojulowo kan (ojulowo eja aro kii fibee tobi o, kekere si ni ori re)
Ina ori ewe sawerepepe niwonba,Ewe eyinolobe niwonba,Ata ijosi eyo 14, Iyere eyo 14, Agbon to
lomi ninu meta

SISE RE
A o lo ata ijosi loto, iyere loto, ewe eyinolobe loto, ina sawerepepe loto, ao fi eja aro sinu isaasun
olomori, ao da gbogbo awon nnkan ti a lo yii lee,a o fo omi agbon kan sii, ao see pelu epo ati iyo
ti yoo jina daadaa. Toba tutu die, ao soo sori osuka aso funfun, obinrin naa yoo je eja yen pelu
gbogbo egungun re, yoo si gbe omi obe yen mun.
Ao fo omi agbon meji toku, oun niobinrin naa yoo fi se omi mun ni aseje naa lori.

AKIYESI
1.Ao gbodo lo omi rara o, omi agbon lao fi se omi fun lilo gbogbo ewe eyinolobe, iyere, ata ijosi ati
ina ori ewe sawerepepe.
2. Awon agbon yen kiise jije fun enikeni o, ao lo sonu ni tabi ka rii mole.
3. Obinrin yen ko gbodo mu omi le aseje yii o, sugbon o le mun schnapp lee lori bobasefe.
4. Aseje yii kere loju, sugbon o soro lati je o. Afi ki e joko ti obinrin yen kí e rii wipe o jetan
patapata o.
5. E gba obinrin.naa niyanju ko mase bi aseje yii o.
6. Iju yii maa yotan diedie mo obinrin naa ninu ni.

IKILO
Ewu wa ninu ise abe sise lati maa gbe iju kuro lara obinrin. Ti won ba see, ó seese kotun hu
pada, tabi ki obinrin tibe di ero orun.

(g) Ao ge pándòrò ati ògèdè dudu kekeke, ao lo obu-otoyo ati kanhun bilala die, ao daa sinu omi
osàn wéwé 2liters, ao ju ose dudu die bii oni #20 sinu re fun 24hrs.
Lilo re; Ilaji cup kan ni eemeji ojúmó leyin ounje fun 1month.

(h) OPOLOPO ENU-KOPIRE, ESO Lára PUPA, Ako Kanwun, OSE DUDU TOPO, AO Jo PO
AO MAFI OTI LO.

(i) Epo egusi pupo, osan wewe gbigbe,kanwun bilala,a o jo won papo,a o ma fi mu eko gbigbona
tabi oti lile.

(j) OYUN IJU EYITI YIO GBE JADE TI YIO LO TE LE AGBO RE TI YIO KOKO FUN 10
DAYS
Egbo orombo topo die, ewe esun pupa, kanhun bilala, ao bu omi si, ao se ni agbo ti yio jinna
daada, mimun ni aaro ati lale fun 10 days

EYITI YIO GBE JADE


Egusi ti owo otun agbaarin pelebe ti aba pa tan, odo ewe ewura topon fooo, kannanjole die, ao
lo kunna daada ao wa su rogodo rogodo kekeke, nigba toba ti mu agbo to wa loke yi fun ojo
mewa,ao tun fun ni ogun eje mu (Blood tonic) fun another 10 days, ti oba ti lo tan, yio mu okan
ninu ogun ti asu rogodo yi, yio ti bo oju ara, alefi nkan ọmọkùnrin ti wole tabi abela kole ba wo
inu lo daada, enina ko gbodo jáde lo sibi kan kan rara o boti le wu kori, eleyi ni yio gbe iju yi
jade. Pelu Ogo Ọlọhun.

EYINI IDAHUN SI AWON IBEERE LORI OGUN IJU TOWA LOKE


1:EWE EESU PUPA ni koriko ti oma nwa ni bebe odo ti oma npon resuresu ama nge fun eran
agbo lati je pelu.2:ODO/OJELE EWE ISU EWURA je eyiti oma npupa ti kogbo ti o kangun
soke ninu ewe ABO ISU.3:EGUSI AGBAARIN OTUN ni oma nwa ninu eso AGBAARIN ti
arare ma ndan ti afi nse Ogun EDA ao yo egusi ti apa otun ninu eso yen lehin ti aba la si ona
méjì.

(7)OGUNWÀRÁPÀ (EPILEPSY)
(a) Iyagbe aja lopolopo,iyagbe pepeye lopolopo,egbo tude,egbo awogba,epakun,ẹnu
kopire,alubosa elewe, adi eyan die,igo omi osan wewe kan,a o lo awon nkan yen kunna a o sa
gbe a o pin si ona meji.
LILORE:A O DA ILAJI SINU ADIEYAN TI ATI PO PAPO MO OSAN WEWE,YIO MAA
FIMU EKO GBIGBONA.

2:A o ge eran maalu si mesan fun okunrin,meje fun obinrin a o ma fi ona kan toku se laseje,adi
eyan ni epo re ó.

(b) OGUN WARAPA TI YI O PO LOJO TOBA LO OGUN YI.

GBOGBO NKAN TOWA NINU ALEGBA AWON MIRAN MA NPE NI ALEPA AO KO SINU
IKE KAN AO RO ILAJI IGO EPO PUPA KAN SI ATI ILAJI IGO KEROSINE KAN PELU
RE AO WA EJA OJIJI OOYE AO RE KEKEKE SINU RE TI OBADI OJO KEJI SI OJO
KETA OTI BERE ISE Nìyẹn.
Note:-ALEGBA NI ERANKO TIWON NPENI AWONRINWON...OMA NFI ARAJO
ALANGBA,AHON MAA NPO NI ENU RE BAAYI....ARARE ASI MAA FIN Tòótó.

LILORE FUN ALAISAN NA


GASI KEKERE Kan, AO fi SI AYE IPAMO KAN TITI YIO PO WARAPA NA KINNI náà
DABI OMONLE NI O TAKO TABO SINI WON OLEPO ABORE OSILE PO AKO RE TI
OBA PO OKAN NINU MEJEJI YI WARAPA KOTUN GBE ENIBE MO.
N,B;- AKIGBA OWO LORI RE O AMAFI NSANU NI O.

(c) OGUN WARAPA PELU OGUNORUU:


Ewe dagunro,eje pepeye,eje alangba ako ati abo,a o lo ewe yen pelu ata a o fi se eje yen lepo
niyo,eni naa yio je.

(d) EBU WARAPA;


AKO ATI ABO ALANGBA,EWE JOKOJE,EWE DAGUNRO,AO JO PAPO,AO BU SINU
ADIN,AO MA FUN ENINA LA HMMM ODAJU.

(e)EBU WARAPA;
OPOLO (FROG) KAN,OSE DUDU,ODIDI ATARE KAN,AO JO PAPO,LILA.

(f)PIPO WARAPA SILE,AGBOSISE;

AO SE OPON-OYINBO(PINEAPPLE) PIPON PELU EGBO AWOGBA-ARUN,EGBO


ODOWO,OTI SHINAP LAO FI SEE,INU KOTO NI YIO POO SI.
(g)PIPO WARAPA SILE,AGBOSISE;
AO FI OMI OSAN-WEWE SEE EGBO ARUNPALE,IMI OJO DUDU,ERU AWONKO,EWE
EFINRIN NLA,ADIN DUDU PAPO,GAS KAN NI YIO MU YIO SI POO SI INU KOTO.

(h)ASEJE ERO WARAPA;


AO LO EGBO IYERE PELU IYERE,AO GE ORISIRISI ONA NI ARA AJA NI ONA
MOKANLELOGUN(21 PLACES)AO FI EPO,ORI ATI EWE TI ALO SEE FUN ONI
WARAPA JE.

(i) WARAPA/OGUN ORU:EWE ODUNDUN,A O LO PELU ATA IJOSI META A O MA FI SE


EJA ARO LERALERA FUN ENI NAA.

(j) ao jo orukudu ọ̀gẹ̀dẹ̀, ewe iyawe, egbo oruwọ́, àti akọ kan hun pọ sì inú ọtí tàbí orombo.
Mímú ni gas kan.

8. OGUN IBA (MALARIA FEVER)


Anabi wípé ibà tí ẹ rí yẹn láti inú iná Jóhánámo ni oru rẹ tiwa, nítorí náà omi ni kí ẹ fi pá oro
iná rẹ (ibn Majjah).

Ṣugbọn omi, agbo, oúnjẹ gbígbóná ni ogún ibà tí òtútù munwa, àwọn olókìkí dókítà Ar Rábì
(Ghalileo) sọpe ibà pin sì ọ̀nà méjì

1. Accidental fever (ibà ojiji), eyiti òru, iṣẹ́ aseju, pipọ́ oòrùn lè faa.
2. Morbid fever (ibà atinu ẹ̀jẹ̀ wa), eyi lè ṣe ènìyàn larin ọjọ́ kan sì mẹta, tí ó bá ti dapo mọ
humors yio yí padà di ọkàn lára ibà wonyi

I. Bilious fever /melancholic fever/phlegmy fever tàbí sanguine fever.


TI mobid fever láti inú ẹ̀jẹ̀ bati sise ibi rẹ dé inú main organ yio di helic fever, eyiti kosi ara ti
kole fi agọ́ ara ènìyàn dá, ó lè bí thyroid tí yio se ọ̀nà mọ iyagbe deede, tí inú yio si má wù, ó lè sọ
ìtó di pipon, ó lè bá ẹ̀jẹ̀ jẹ, ó lè di minmin pelu ọkàn lọ́wọ́.

Àwọn oníṣègùn oyinbo fi yé wa wípé yanmun yanmun kan tí orúkọ rẹ njẹ ANOPHELES tí ó má
npọ́ àìsàn burúkú kan tí orúkọ rẹ njẹ PLASMODIUM / FALCIPARUM sínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn ló má
nfa àìsàn ibà malaria.

Malaria/ibà burú débi wípé ó má npa million lọ́nà ọgọrun marun ènìyàn larin odun kan.
Nitoripe agbára tí ó wà nínú ẹ̀jẹ̀ ara ènìyàn tí anpe ni RED BLOOD CELL Ní àìsàn yí má ń
gbógun ti yio si sọ ẹ̀jẹ̀ di kìkì àti òní koko, eyiti kò ní mún kí ẹ̀jẹ̀ ó lè rí àyè san nínú ìṣàn ara
gbagbọ ara yio si gbóná, èyí sì lè fà dídá kú tàbí òde orí, ìdí nìyí tí wọn fi npe ni cerebral maleria
ibà tí onko wàhálà bá ọpọlọ, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ibà thyroid.
Typhoid jẹ kòkòrò burúkú inú ẹ̀jẹ̀ tí wọn npe ni SALMONELLA nfa, èyí tí ó lè bá ẹ̀jẹ̀ ènìyàn jẹ,
nitorina tí ibà kan bá yọjú, ó yẹ yẹ a ṣe ayẹwo láti mọ irúfẹ́ ibà tí ńṣe, àwọn ayẹwo tí a ni lati se
ni a pè ní MALARIA PARASITE ÀTI WIDAL TEST kí a má bá fi ogún lakuregbe wo warapa.
Àwọn egbògi wá yí lè koju eyikeyi ibà tí kiba jẹ́, kí a sì má gbàgbé wípé kosi nkan ti àwọn mumy
wá ó lè towọ́bọ́.
OGUN IBA
(a) ewe owuu ati osan wewe, ao agbo paapoo. Ao waa see leyin naa aoo mún.

(b) gbo efo ugu . ( ewe rook ) yo omi re . po papo mo eyin adie ibile ati omi osan wewe pelu oyin
igan sibi meji . po papo ki o gbd mi ni eekan soso . se be ni igba meji loojo . laaro ati ni ale . si ise
yi fun ojo meta.

(c) Ao wa ewe eyinolobe ao sa ti yio gbe dada ao wa lo ti yio kunna ao da sinu oti ao ma mu
diedie, mofi olorun bura mi o ni aisan meji ju iba yi lo toripe genotype aa nimi bi ogun sekere
to oni mo ma n lo sì.

(d) ewe elu,ina tannagbowo,eru alamo,eyin ope,ao gun po,ao nigun ekuro mo o,ao po lose ao
bere wiwe re leyin ojo keta pelu kankan titun,gbogbo iba arawa ni yio ko danu.

(e) Agbo iba ponju


Epo ahun, epo mango, ati doctor Igbo, aoki sinu koko pelu Emu ogidi tabi omidun, aose jina
aomamun laro losan lale.

(f) OGUN IBA TYPHOID:-


ao fanta igo kan ewe asaa mimu lilo ao dasinu redi ojo keji ao se idotire danu ao mamu diedie
lemeta lójúfò.

(g) itakun itapara, eepo amujẹ́, ọsan wẹ́wẹ́, ao gé tẹ́lẹ̀ ìkòkò, ao fi omi ṣe jìnnà mímú ni
gbígbóná.

(h) ọ̀sán wẹ́wẹ́, ao gé sì méjì-méjì, ao dá ojú rẹ dé ìsàlẹ̀ òru, egbo orogbo àti èpò awọ́pa, ao kò lè
lórí, ao bù omidun sì ao ṣe laagbo ao má mun.
(i) ewe dagunro, ewe ìyá, erele èwe ibẹ́pẹ́, oruwọ́, dongoyarọ,ewe ọsan wẹ́wẹ́, ao ṣe laagbo,
Mimun àti wiwẹ́.

(j) wiwẹ́ ibà ògbólógbòó danu


Ewe kọ̀leọ̀rọ̀gba tútù, ao wa fi ẹyin adìẹ ìbílẹ̀ tútù kan tẹ́lẹ̀ ìkòkò, ao wa se agbo yẹn yio dúdú
daada, ao wa kainkain ìbílẹ̀ tuntun, pẹlu ọ̀sẹ̀ Abuwẹ́,tí ó bá di ìdajì kùtùkùtù, tí àwọn eyan ó ti
má jáde, ao gbé ìkòkò agbo náà lọ sí àárín ojú ona ti èrò ngba, ao bo ara silẹ ni ihoho, ao kò
gbogbo èwe agbo yí sì ilẹ̀lẹ́, tí yio kú ẹyin àti agbo nínú ìkòkò, ao dúró lórí èwe, ao fi agbo wẹ
pẹlu ọ̀sẹ̀, ao wa bo ẹyin ìsàlẹ̀ koko yẹn ni ihoho, naa, ao ju sì ẹnu ni ekan ṣoṣo, ao kò eepo rẹ àti
kainkain tí a fi wẹ leri èwe yẹn, ao wọ́ aṣọ, ao kúrò nibẹ.

(9) OGUN JẸJẸRẸ (CANCER)


Arun jejere ni ale pe ni EBORA ninu awon arun to ma nse ni ni ago ara latari IDAGBASOKE
aibojumu to ma nsele si orirun tabi ipile eya ara(body cell)idi ti nkan yi se ma nsele ni wipe ipile
eya ara ti ongbe ninu apo felefele yi gbodo dagba ki osiku ti oba to asiko kan ki omiran tun bere
ise sugbon latari awon akoba kan eya ara yi koni ku yio ma dagba nitire ni ti yio si tun ko ile
sinu ago ara.
Awon omo to kojo sinu ile naa ni a npe ni ARUN JEJERE.
Siwaju sii,eyi ti oba wu GONBU sojukan ninu ara ti ko raye se akoba fun eya ara miran
gege bi ori,oju,eyin e.t.c ni alepe ni abo jejere(BENIGN) eleyi rorun lati se itoju re,sugbon eyiti
oba ti papo mo eje ti oti bimo kaakiri ago ara ni a n pe ni AKO (MALIGNANT)eleyi gangan ni
alepeni HIRE ASSASIN tabi ASEKUPANI nitori eleyi ki ngbo itoju rara ki Olohun gbawa lowo
iru Aisan bayii o.
OGUN CANCER
(a) Ewe arunyanyan pupo (awon kan npe ni ewe arunpale), eeru Alamo pupo, ao se mejeeji yii
pelu omi tomo daadaa ninu oru tabi kolobo nla ti yoo jinna daadaa.

LILO RE
Alaisan naa yoo ma mun ni glass cup nla kan lemeeta lojumo fun ogbon ojo leralera (30 days
non-
stop) yoo si ma fi we pelu. Toba sa, yoo tun se omiran. Awon kokoro to nje eyakeya ninu
ara yoo ku, alaisan naa yoo sigba itura alaafia.

(b) Eepo igi eeru, alubosa elewe, a o gun mose dudu, a o maa fi fo oyan yen.
(c) Ewe efinrin tutu, eeru awonka eyo meje, ata ijosi die, a o gun papo mose dudu, a o maa fi fo
oyan yen.

(d) Ogede omini to pon, a o bo eepo ara re danu, ewe asunwon, eeru awonka pupo, a o see pelu
omi- mimu ni leemeta lojumo ni gaasi kookan.

(e) Eso bomubomu ati ewe re, ewe isepe agbe, ewe lapalapa eyikeyi,, a o see pelu omi, a o maa fi
fin oyan yen ninu koroba, a o gbe oyan yen sinu koroba, ooru agbo yen yoo maa se sii lara.

(f);AO RE CARROT WEWE,AO SEE PELU ALUBOSA AAYU LILO,PELU OMI OSAN
WEWE AO MA MU DIEDIE.

(10) OGUN AWOGBA ARUN


(a) Alubosa Aayu lilo, Oyin gidi, Olive oil, or Zaetuun, Aopo papo, aomamu diedie, lase olohun,
onsise fun iko eyikeyi, Mimi fukefuke, irore, ofinkin, iba eyikeyi, Arariro, nkan osu obinrin
tikose Dede, kidney problem, idakole, Aran eyikeyi, etc.

(b) OGUN GBOGBONSE ARUN:


OSE DUDU,OGIRI IJEBU,AKUKO ADIE NLA KAN,EGBO INABIRI,EWE JOKOJE.AO FI
OLO LU INABIRI YEN AO YO IGI AARIN RE DANU,AO KO AWON NKAN TO WA LOKE
YII SINU ODO,AO PA ADIE YEN AO DA EJERE SINU ODO YEN,AO LA INU RE AOKO
GBO NKAN INU RE ATI IJOKA RE SINU odo yen aowa gun papo no ose dudu AO ko SINU
isasun olomori AO GBE pamoo.
Ao po sinu oti Ao maa bu fun aisan ao má.

(c) AWOGBA ARUN.


AO LO ALUBOSA ELEWE PELU ERU ALAMO PAPO, AO WA POMO ORI. AO TUN WA
LO KANFO ATI KAFURA PELU IYERE OSUN, AO TE NI OTURA MEJI SI APA OTUN,
OSA MEJI SI APA OSI. AO WA PE GBOLOHUN RE SI: AKUWARAPA ESE AJA, IJAKUMO
ESE MALU, ANI OKAROGUN ONI OUN LO, ANI OKARODO ONI OUN RE, ANI OKALO
OKE IGANTI NI ILE BABA AGBON MEREGUN ONI OUN ONI ERU RU LAILAI, WONI
ISE KINI YIO MASE, ONI ARUN TI ENIKAN OMO OWORE, TI ENIKAN OMO ESE RE NI
OUN MAA WO, WONI BAWO NI YIO SE MAWO, ONI ALUBOSA NI OUN OFI MAA SA
DANU, WONI EYI TOBA SAASAA TI O SATAN NKO, ONI ERU LOUN OFI RU DANU,
WONI EYI TOBA RU DANU TI O RU DANU TAN NKO, ONI KANFO NI OUN O FI MAA
FO DANU, WONI EYI TO BA FO DANU TIO FODANU TAN NKO, ONI KAFURA LONI KO
RAA, OTURA MEJI LONI KI ARA OTU L/L, OSA MEJI LONI KI OSA GBOGBO ARUN
ARA L/L DANU. AO WA DA SI INU ORI YEN. AO MA FI SI EKO GBIGBONA MU, AO SI
TUN MAFI PA OJU IBI TON DUN YAN. OPARI OLOUN YIO JE OBARAMU. N:B EJO ELO
BERE AWON ESE IFA YEN LODO AWON TOMO.

(d) AOWA IFUN OKETE OOJO.AGOLO EYO ATARE KAN. AGOLO IYERE KAN. EGBO
AKEREJUPON. EGBO IPETA. EGBO EGBESI. TABA JUKU. TABA SONBO. TABA
OYINBO. AODA GBOGBOE SINU OGOGORO IGO MEJI.PELU ADI IGO MEJI. AO MISS
RE PO NIO.AOMAWA YO MUN Diedie.

(e) EGBO IFON, EGBO TUDE, ORO AGOGO, ORO ADETE, ORO ALABEBE, ENU OPIYE,
EGBO AWOGBA ARUN, EGBO GBOGBO NISE, EKU ASIN META, ISETA ODIDI KAN,
IKANDU PUPO, ERU ALAMO, AOWA LOWA ADI EYAN GIDI IGO MEJI, EPO PUPA IGO
MEJI, OPOLOPO OORI, AO KOKO FI ODO GUN GBOGBO AWON INKAN YI DIE DIE,
KI ATO WA SE, EPO ATI ADI ATI OORI YAN NI AO FISE O, AKO GBODO FI OMI SE O,
IKILO, TI ABA NSE KOGBODO RU PANA, GBOGBO AISAN NI ONSISE FUN, A O MAMU
DIE DIE, TI OBAJE OFA NI AFE LO FUN KI AMU NINU AGBO YI, KI ATUNFI PA OJU
OFA NA, ATI BEBE LO.

(f) Alubosa elewe topo,Egbo asuhan topo,Orogbo 11,Atare 11,Baka 11,Sugar st Louis pali 1,Eso
awogba arun die,Epo pandoro die, ati ewere,Egbo abo pupo,
Kanhun bilala niwanba,AO gun gbogbo wan papo, ao sa gbe ao tun gun kunna aowalo lo ni ero
kokunna Dada, aomafimu eko gbigbona.
kosi aarun na ton dawa laamu ninu ara tikoni wosan.

(g) AO MIN OSAN TANJARIN IGO MEJI.OMIN OSAN MUNMUN IGO KAN.OMIN OSAN
WEWE IGO KAN.KANAFURU AGOLO KAN. IYERE AGOLO KAN.ORI SEBE KAN. ORI
OKA KAN. ODIDI EJO PARAMOLE KAN.EYO ATARE AGOLO KAN.ATA IJOSIN AGOLO
KAN.AOGUN WON KUNA PO DADA. AO WA DA SINU. KOKO KAN. AOWA TU GBOGBO
AWON OMIN OSAN YEN SI.AOWA SE TIO JINA DADA.......AOWA DA SUGAR PALI KAN
SINURE TOBA JINA TAN. AOBAWA TUTU AO RO SINU IGO KAN. AOMA MUN NI SIBI
Kokan.

(h) IWOSAN ARUN TI AKOMO OJU RE:


EPO IGI KASIYA,EPO OKEDO,OPOLOPO ALUBOSA AAYU,KANAFURU LOPOLOPO,A
O GE GBOGBO RE SINU APE,A O WA OPOLOPO ORONRO MAALU,ILAJI IGO ADI
EYAN,IGO OMI OSAN WEWE KAN,IGO OTI KAN,IGO OMI OSAN IJAGANYIN KAN,A
O SE GBOGBO RE PAPO,AO MA MU NI ILAJI CUP NI EEKAN SOSO LOJUMO.AISAN
NAA YIO LO,LEHINNA KI AWA AGBO EJE TO DARA FUN ENI NAA Ó.

(i) EWE ASURUN OYINBO ATI TI INAGO ATA IJOSI DIE KANWUN TOLE DUN SUGAR
DIE IYO DIE AO KORE AWON EWE YEN WEWE AOSA GBE AOLO KUNA AOWAGUN
AWON TOKU YENPO KOKUNA AOWA DAPO AORO SINU IGO AOMA BUFUN WON LA
DIE DIE AGUNMU YI AWOGBA ARUN NIO OSI DAJU

(j) AWOGBA ARUN.


Alubosa funfun, ati erun aworinka, ati kanhun bilala, Ao DA gbogbo re sinu odo , Ao gun papo,
Ao sa ti yio gbe dada, ao ma bu sinu ike kan, ao ma nu omi so ti obawa di ojo keta, ao ma mu
larolaro ati ni ale...... Odara fun eniti onbe olorun fun omo. yio ma mu ni gasi kokan .. ti obari
nkan osu re yio ni orun lagbara olorun.

(k) GBOGBONISE ARUN NINU ARA:Ewe taba tohu si ara ile,eru alaamo,ikun ojia aogun
Papo tiyoo kunna dada pelu ose dudu ao ko ose yi sinu Iwo malu aosokun mo leti ao gbeko sita
ile wa Lilore: aobu ose yi die sinu oti ibile tabi HOT enikeni ti aisan tabi arun kan ba nda laamu
ninu ago ara re yo mamu gaasi kookan ni emeji lojumo yio baramu ooo Iree.

(11) OGUN LOBUTU


(a) OGUN LOBUTU TABI OFA AGBA:
Ao sun iku ninu ina,koro eru lopolopo,ao ha egbo atapari obuko sinu re ao lo papo mose ao mafi
pa oju lobutu yen.

(b) POWDER LOBUTU TI ANFI OTI TABI EKO GBIGBONA LO.

ESO PANDORO KEKERE KAN KANUN,BILALA OBUOTOYO OSE ALADI DUDU AJOPO
AO LO KUNNA AORO SINU IGO KAN TABI IKE KAN OTI TABI EKO GBIGBONA NI
ENINA YI OMA FILO.

(c) AGBO LOBUTU


EGBO IFON EGBO IPETA EGBO AKO IBEPE EGBO OKAN EGBO INABIRI EGBO TUDE
EGBO EWURO OKO EGBO EWURO ILE ALUBOSA ELEWE PUPO ERUN EELA AO FI
OMI LASAN SE LAGBO N,B ,ENITI AISAN YI BANSE YI OMAMU YI OMA FIWE.

(d) OGUN LOBUTU/EJE DUDU:


Egbo saworo ati epo re,epo olobiedun,itaku ipa,epo oloja ona,epo ope,ewe agunmona,eso agba
meta,a o se gbogbo re lagbo a o maa mu,yio ma fiwe.

(e) AGBO LOBUTU TI AO MA FI JO ATI MIMU RE.


EGBO OGIRI SAKO WA KOPO KO SINU IKOKO BU ATASI KOPO AO BOMI LE LORI
AO SE JINA DADA AO MA YO OMI RE, AO MA FI JO OJU IBE,BI ABA FE KOTETE SAN
KI ALÁÌSÀN MO MU OGEDE OMI YI LAI KOGBODO MU OMI MIRAN YATO SI OMI
AGBO YI.YOGBA DUN WERE WERE PELU ASE ỌLỌHUN.

(f) AGUNMU LOBUTU


ESO IGI BONI,EGBO IGI ASUNWON TIWA,EGBO INABI,EPO IGI PANDORO,EGBO IGI
DOGO KIYAN,IRU PETE,IYO,BAKA,ATA DUDU,EYO ATARE TOPO DADA,ALUBOSA
ELEWE,JAHUNKAWO AO GUN GBOGBORE PAPO FIFI MU EKO GBIGBONA.
(g) AGBO GBOGBONSE FUN AKO LOBUTU/JEJERE/KOKORO INU EJE:

EGBO AGBESI,EGBO ERUJU,EGBO GBOGBONSE,EPO GBOGBONSE,EPO


AROJE,EGBO GBEWUTU,EPO OGANWO,EGBO AROJE,EGBO MISINMISIN
GOGORO,EPO PONHAN,A O SE LAGBO ORI INA,A O MAA FI WE, A O MAA MU.

(h) EKU ASIN KAN,IGI AKA,A O JO EKU ASIN YEN,A O SUN IGI AKA NINU INA,A O LO
PAPO MO ETU IBON,A O DA MO EKU ASIN TI AJO YEN,A O PIN SI ONA MEJI,A O PO
ILAJI MO EKO ELEWE A O MA FI PA IBI TOWU YEN,A O DA EYI TOKU SINU ADI
EYAN,A O MAA MU NI SIBI LAARO/LALE.

(i) AGBO LOBUTU ATI SANGUNSANGUN:


EPO OROGBO,EWE AGBARI ETU,OMIDUN NI A O FI SE A O MAA MU LOORE KOORE.

(j) ao fi omi ṣe eepo igi gbogbonise,àti epo igi irẹrẹ pọ mímú àti wiwẹ́.

(12) OGUN INU RIRUN


(a) ifun adie,ewe amunimuye aojo papo aoda sinu adi eyan aoma LA.
(b) OGUN INU RIRUN.
Eso akerejupan.
aogun, aolokunna, aomdasinu oyin, aomalaaa, yiolole pelu ogo oloun.

(c)INU RIRUN
Abeere,egbo akogun,egbo sirigun,paran pupa ati funfun,alubosa elewe,ao fi tele ike EVA ao ge
nkan toku lee lori ao bu omi sii ao gbe pamo fun ojo meta ao maa mu die die.

(d) ITOJU AISAN INU .


sugar idaji pali kan, omi osan wewe igo kan, omi osan mimu igo kan,
omi osan jaganyi igo kan, omi osan grape igo kan, lọ ata ijosi eyo mewa sinu rẹ, lọ alubosa elewe
idi meji
DA GBOGBO RE POO . SE NI ORI INA FUN OGUN ISEJU ( 20 MINUTES ) FI ASE SE KI O
RO SI INU KEG . maa mu ni gaasi kookan ni aaro ati ni ale . gaasi meji . meji . ni aaro ati ni ale
fun agbalagba . o kappa gbogbo aisan inu . IROYIN OTO AF ojú bá.

(e) Ao lọ baaka, atare àti Ata ìjọsì sínú omi ọ̀sán wẹ́wẹ́, mimun tí inú bá fẹ́ má rún ènìyàn.

(f) ao lọ ẹnu ìbọn àti Akọ kanhun sínú oronro maalu, síbi kan pere ni mimu rẹ.

(g) ao fi omi gbó èwe epin'lẹ́, ao fọ́ ẹfun lẹ́ sì mímú.

(h) Ao jo kaa-kaa ọ̀gẹ̀dẹ̀ omini (orukudu) pẹlu akọ kanhun, líla.

(i) ao lọ ọ̀tá inú ìrókò lọtọ, ao jo ìyẹ́ igun sì, ao má là.

(j) Egbo gbegi, ọ̀tá inú ìrókò, atare jíjó pọ líla.

(13) IKỌ̀ ỌMỌDÉ


(a) OGUN IKO FUN OMO KEKERE:
A o re epo orogbo ati ibiti oma nro lara aridan olorigun sinu omi,fun opolopo wakati,a o wa bu
die sinu sibi a o fi oyin si,a o fun omo naa mu.

Note:E lose ayewo okunfa iko naa lona igbalode ó.


(b) OGUN IKO OMODE
Ao gun orogbo koniyee kuna ninu odo ao da sinu ike eva water kan ao daa omi osan wewe
tiwon o ti daaa omi lu .. ao fipamo fun ojo meta ao ma fun omode ni sibi kekere mun.

(c) OGUN IKO OMODE


OYIN IGAN GIDI,A O GBO EWE EWURO A O FUN OMI RE SINU OYIN YEN,A O DA
OMI OSAN MIMU SINU RE,A O PO PAPO.A O MAA FUN NI SPOON KEKERE MU.

(d)OGUN IKO OMODE


ewe taba tutu ao gbo laifomigbo.ao se sibi kan ao wa da oyin igan na si.yio malo nisibi omode
laaro kutu, olebi osilemabi yio sun dokandokan.

(e) OGUN IKO OMODE


EPO IYEYE,EPO IGI TETEREGUN,EWE OMISINMISIN,SUGAR DIE,AO KI NI AGBO,AO
SE JINNA DADA,ODI MIMU,OMODE SIBI NLA KAN,AGBALAGBA SIBI NLA MEJI.

(f)OGUN IKO OMODE


Eepo igi Bọdunbawọ, epo Abadu, Alubosa elewe, ẹẹru, orí, ao ṣe papọ, ao má fún ọmọdé náà
diedie.

(g) ao ṣe igi ogurọ pẹlu orí pọ yio má mun diedie.

(h) Ao ṣe igi ooro pẹlu eérú àwọnka pọ ao má rọ ọmọ náà.

(i) ao lọ egusi inú agbaarin pẹlu iyọ̀ àti orí líla.

(j) ao jo ẹ̀ẹ̀rú nìkan sínú epo pupa, líla lera lera.

(14) OGUN IKO


(a) (OGUN IKO EGBE TABI AIPERI)
Egbo Ipeta Egbo Ifan Ireke Iseta Alubosa Elewe Topo Dada Aogun Po Aofun Omi Inure Sinu
Igo Kan Amamu Die Die Akogbodo Delenu Koma Barun Dànù.

(b) ITOJU IKO ASTHMA


Ao po omi fun fun ti o wa ni idi igbin po mo oyin igan ti o mo ni iwonba . maa la ni wakati
wakati .
(c) Oogun Iko Tuberculosis:
1.Atare
2. Ata ijosi
3. Aayu
4. Egbo Igi Guava gbigbe
5. Egbo Igi Cashew gbigbe
6. Alubosa Elewe
7. Ojere epo
8. Iyo
Ao lo 1 to 6 po ni ori olo gege bi a se ma nlo ata lori olo. Ao ge eran maalu bi oni #500 tabi iye ti
owo wa ka si mesan fun okurin, meje fun obirin, ao gbe ogere epo pupa ka ina lori adiro sugbon
a ko ni je Ki o gba o. Ti o ba ti gbona di e, ao da elo ti a lo lori olo si pelu eran ti a ti ge. Ao je Ki
o so papo fun igba di e Ki a to fi iyo si Ki o le ni adun. Ao je ki o jina daada. Eni to ba ni arun yi
nikan ni o leto lati je obe yi. Ko si ohunje ti ko le fi je. Arun na yio poora pelu Ase Edumare.

(d) IKO TOPO TOTI SO OLUWARE DI Funfun.

EPA BOROBORO TOPO DAADA,ODIDI ISETA KAN,ODIDI ATARE KAN,AO JO PAPO,AO


LO YIO KUNNA DAADA.
LILORE:- EYIN ADIE MEFA AO FO AO FI OSUNWON KAN WON,DEDE OSUNWON
TOBA WON NI AO FI WON OYIN OGIDI TI KONI JURAWON LO AO PO PAPO AO BU
SIBI OGUN YI MEFA SI AO POPO AO RO SINU IGO KAN,SIBI KAN (1 SPOON) 3X Daily.
(e) Iko TOPO
OROGBO, KAFURA ,ALUM LO WON PO KOKUNNA DADA DA SINU Igo KAN AO RO
OMI LE LORI TITI DI OJO KEJI AO MÁ MUN LE MẸTA LOJUMO. 3TIMES DAILY

(f) IKOTOPO
AIDAN,IMIN ORUN DUDU,ETU IBON,LO WON PAPO FUN OMI OGEDE ODO LE LORI
NINU IGO KO MAMU NI OJO 3-3 IKONA YOSI SAN PELU OGO OLOUN
(g) IKO IGBALODE
IGI TETEGUN TI AFI EWERE SI OROGBO LETI ODO NI NGBE AO BE EPORE
KURO,IREKE AO BE EPO RE KURO,EGBO KOKO EKAN,EWE OMISINMISIN IDI (7)
FUN OBINRIN (9) FUN OKUNRIN, OGEDE WERE PUPA KO GBOGBORE SINU ORU FI
OMIKAN EKO SE KOJINNA MUMU LEMETA LOJUMO
IKOTOPO FUN OMODE ATI AGBA
TETEGUN TOWA LETI ODO BE EPORE KURO,IREKE BE EPORE KURO,EWE IJOGUN
IDI 7/9 FOKUNRIN ATI OBINRIN,EWE OWE AHUNBE KOGBOGBORE SINU ORU FI
OMIKAN EKO SE JINNA DADA MIMU 3X Daily.

(h) ERO FUN IKO KODA KOJE AFISE:-


ekun asin gbigbe kan,oga gbigbe kan,eso werenjeje topo die,eso idoro topo die,odidin atare
NLA kan,a o gun papo,oto to lama gun oooo,a o wa dapo,a o wa da sinu adin eeyan dudu,eni ti
iko nse na yo ma mu ni alale,pelu ogo olorun koto pe ojo mejo Alafia yo de ooo.

(i) Oogun iko to daju>


Ao loo wa aidan ti kogbe tan
ao ha ibi isu re ao ki sinu ike kan, alubosa
elewe,ao da omiikan(omi ogi) le lori, ao je ko toro
di bii irole ojo ti aki tabi aaro ojo keji. Ao maa mu laaro ati ale.

(j) OGUN IKO TOBALE


EKU ASIN 7 OGA GBIGBE 7 ERUALAMO AOGUN AOKO SINU ISASUN AOSE ADIN EPO
ORI SI AOFIIN AOMALO SUGBON KIATO SE OGUN YI AOKO RA ERAN MALU NIWON
BA AOFI SE IPESE FUN AWON IYA PELU EPO PUPA AO SE ADURA KAGBADUN NINU
AISAN Na.

(k) OGUN IKO EYIKEYI TI WON TI WO TI KO LO:


Ewe papasan,ewe rinrin,igbin kan,ijapa kan,oga aye kan,ori oka gbugbe kan,odindi atare
kan,ota inu iroko,eru awonka lopoopo,a o jo gbogbo re papo,a o ma fi oyin igan gidi loo laro,a o
maa fi epo pupa loo lale.

(l)OGUN IKO EGBE(Tuberculosis):


Itaku iroyin,epo igi orogbo,etu ibon,osan wewe,osan ijaganyin,isumeri(ogede odo)isu pasan
koriko,isu ego,a o ge awon osan yen si mejimeji,a o fi eru tele ikoko,ao se lori ina pelu omi,yio
maa mu diedie.

(15) ARUNSU (DYSENTERY)


(a) OGUN ARUNSU.
OJIA AO LO DADA,AO SE EYIN KAN,AO FI PUPA INU RE KO OJIA NA JE LALE.
(b) ao fi omi gbó èwe ailu, ao fi omi na ṣe ìṣù ewùrà ni àṣàrò.

(c) ao lọ èwe oriri ao fi se igbin ni ase jẹ.

(d) ao lọ ọ̀mùnú èwe igi ọmọ, ao fi se àṣàrò ọ̀gẹ̀dẹ̀ agbagba dúdú.

(e) omi inú èwe ogirisako (igọ), ao lọ ao fi se ẹja arọ jẹ́.

(f) ao gbó èwe oruru, (omunnu rẹ), ao fi mun gari.

(g) ao lọ ẹran labẹ (ọbọ́) gbígbẹ́ pẹlu irú wooro, ao fi fọ ẹ̀kọ́ mun tàbí kí a má là.

16. AWOKA
(a) OGUN AWOKA GBOGBO ARA.

AFOMO IGI BOTUJE FF,IYERE OBE,AO DA SINU IGO,AO DA ITO AKO MALU SI
LORI,LEHIN OJO KETA AO MA MU,AO TUN FI PARA.

(b) OGUN AWOKA:


EGBO AKOGUN a o gu kunna daadaa,a o fi ori amọ po,a omaa fi wo ese naa wa sile.

(c) :AGBO RE:Ewe agbari etu,egbo osan wewe,osan ijaganyin meji a o laa si mejimeji,a o fi omi
dun se papo,eni naa yio maa yomu.

(d)Egun ese aja,egbo awogbaarun,alubosa elewe,etu ibon eyikeyi,egbo ato ati ewe re,opolopo
eyo atare,a ogun won papo a o sa gbe,a otun gun kunna,a o ro sinu igo kan.
LILORE:A O SIN GBENREN SI ESE ENINAA MEJEJI TITI DE GBOGBO ITAN RE A O FI
NKAN YEN KUN,AO PO DIE LORI,A O MAA FI WO ESE YEN,YIO MA FI EYI TI OKU
MU EKO GBIGBONA.
(e) OGUN AWOKA

AGBO RE:-Egbo senifiran ao se pelu kaun die,


kafura pelebe omi lasan lao fi se ki eni na ma mu

(f) OSE ATI IPARA RE;- Ewe aluro, ewe padimo gbigbe ni mejeji o, ao gun po ao pin si meji ao
fi apa kan po ose dudu ao po ida keji mo ori, ao má fi Ose yen we ibiti awoka na wa ao wa fi nle
fún bi ogun iseju kia to we dànù ao wa fi Ori pa ojú ibẹ́.

(g) AGBO AWOKA TO Dájú.


EGBO AKA, EGBO OSHUNSHUN, EGBO IDIAPATA, EGBO IYERE OSUN, EPO AGANO,
EPO OROGBO, EPO AHUN, ERU AWONKA, OSAN ORONBO WEWE ATI EGBOE,OSAN
IJAGANYIN ATI EGBO E, KISE DANDAN KI OJE WIPE EGBO OSAN ORONBO TI
AFELO GANGAN NI A O MAWA EGBOE KAKIRI O, ALERA AWON OSAN YI NI IBIKIBI
TI ABATIRIWON, KI ASI TUN LORA AWON EGBOYI NA NI IBIKIBI TI ABATIRI AWON
NA, EWE ARUNPALE, EWE AHUN, EWE EFIRIN OSHO, EWE IRANJE, EGBO ATAPARI
OBUKO, A O SE NI AGBO, KI ENING MAMU.

(h) Awoka.
a o wa mudunmudun inu egungun itan malu. Ao ko jade sinu ike kan a o tan petrol die si a o po
po dada a o po mo ori a o ma fi wo ibe .isale ni a o ma wo si ó.
(i)OGUN AWOKA/SANGUNSANGUN

TẸ́WỌ́GBOYÈ ARUNPALE,EWE AGBARI ETU,EGBO INABIRI,MUDUNMUDUN ESE


MALU,KAFURA PELEBE A O GUN PAPO MO ORI,A O MA FI WO ESE YEN.
(j) OGUN AWOKA TABI ARUNMOLEGUN.
OBI ABATA MERIN,ATA ILE MERIN,ATARE MEJI,IYERE,EWE EFINRIN,OROGBO
MARUN,AO LO GBOGBO RE PAPO,AO DA SINU OMI OSAN WEWE,AO MA LO SIBI
MEJI NI ARO ATI ALE.

(17) ÓGÙ ORU


(a) OGUN TAFI NWO OGU ORU
ITAKU BOMUBOMU AOFI EERU 7 FUN OBINRIN AOFI 9 TELE FUN OKUNRIN
AOMATO SI INU AGBOYI TI ITOYEN BATIRE AONI KOMA BU AGBONA MU NI
AROKU TU ITO YEN LAOFI RE OMI MIRAN KO GBODO KAN SI, KIARI WI PE ENITI
AMAFI ITORE SE AGBOYI KONI ARUN KAN LARA Ó.

(b) WARAPA/OGUN ORU:


EWE ODUNDUN,A O LO PELU ATA IJOSI META A O MA FI SE EJA ARO LERALERA
FUN ENI NAA.

(c) OGUN OGU ORU/WARAPA:


Egbo eesu pupa,egungun ako,egungun owiwi a o lo papo a o fi sin gbenren yipo ori eni naa.

(d) Egbo wowo, èso oriri, odidi ejò paramole, tàbí ejò ọkà, ìfun abo alangba, irẹsi àti atare mẹta
jíjó pọ, ao pò mọ orí àmọ́ díẹ̀ fún Ipara, díẹ̀ sínú ọtí tàbí omi ọsan wẹ́wẹ́, Mimun tàbí kí a má là
bẹẹ.

(e) eepo wowo, egbo arunjẹran, ìfun àkùkọ, àti ìfun abo adìẹ, ao jo pọ̀ ao dá sínú adi ẹyan,
pipara.

(18) LUKUREGBE
(a) AGBO LAKUREGBE:
Epo igi ahun ao lookunna ao ma fi mu ogi gbigbona.

(b)LAKUREGBE/AWOKA:
EWE AGBARI ETU,EPO OROGBO,OSAN IJAGANYIN MEJI,AO LASI MEJIMEJI,AO FI
OMIDUN SEE MIMU LAARO LALE.

(c) Egbo inobiri aolokuno Dada aodimo owo no.pelu aso tabi bandage. Aowa ma fi ra ino diedie.

(d) Egbo arunpale, ẹẹruju, ọ̀gẹ̀dẹ̀ omini pipon, egbo ifon, egbo àwogbà run, epo igi agbonyin,
ẹẹru, alubosa ao ṣe Mimun.

(e) egbo atapari òbúkọ, egbo tude, egbo ifon, pakun ewọn agogo, Aidan, ao gùn pọ pẹlu ọ̀sẹ̀
wíwẹ́.
(19) Oówo/Eewo (BOIL)
(a) GBOGBO NTIMO NDUNNI TABI TI MO NRO NI BI OOWO {BOIL}
AKANDUN,OMUN DUDUN TI OMO KOBA LE mú.

EWE SABALE,EWE BORO TI AMA NFI ESE NU BI IDOTI BAYI NI LESE NI NJE EWE
SABALE,EWE EMILE,EWE EWURO,ERU ALAMO,AO GUN ORISI METETA PAPO,AO
PO POMO OSE DUDU,YIO MO LE MO GBOGBO OGANGAN IBE YIO FI BANDAGE WE
YIO FI MORA TOBA SE WIPE ODI ETUTU SINU TELE TELE KO GBODO JU BEE LO TI
YIO FI TU PELU OGO OLOHUN

(b)OGUN WITHLOW:
ETU IBON,ALUBOSA ELEWE,EYO ATARE,ORO ALAGOGO DIE,AO GUN PAPO
MOSE,AO MAA LEMO OJU WITHLOW YEN.

(c) OGUN FUN ENITI OOWO MAA NMU NI GBOGBO Igba.


Ewe rere eyikeyi tutu ao lo kunna daada ao popo mo ogi tutu aofi po eko enina yio mu pelu ogo
olohun koni dalamu mo.

(d) Oogun eewo/oowo(boil)-


a o Jo igi ewuro pelu epo igi Tara po,a o fi adi-eyan po,a o ma fi pa oju rẹ.

(e) Ao lọ ẹfu- oke, èwe iná àti atare gbẹdẹgbẹdẹ, fifi PA oówo náà, tí a kò bá rí èwe iná tútù, ao lo
gbígbẹ ao fi ori pẹlu rẹ ó.

(f) eewo lásán.


Ao lọ egbo akerejupon sínú orí fi fipá.

(g) With low:


Ewe munutoro,omunu ewuro,eyo at are,aolo papo mo ose ao maa le mo loju.yio gbe danu

(20) AKOKORO

(a) AKOKORO
OKO OGEDE WERE TOGBO,OKUTA AKO TODA DURO FUNRARE,EPO IGI
ODAN,OJOTI ABA BERE OGUN YI NI AGBODO PARIRE,AO FI OKUTA AKO TELE AO
GE ISANA OGEDE YI WEWE AO KOLE AO KO EPO ODAN YI LE MOLE AO BU OMI O
JOO SI AO SE JINNA DAADA YIO MA DI SENU TOBA TUTU DIE KO MO GBE KANA NI
GBOGBO IGBA TOBA FE DI MO ENU KOLE DI MENU JU IGBA MEFA LO TI YIO FI Ṣàn.

(b)AKOKORO
EweGUAVA,ERU AWONKA,ALUBOSA AAYU,AO SE WON PAPO,ENI NAA YIO MAA LA
ENU SINU RE NINU CUP,YIO WAA MA DI DIE SI ENU PELU.

(c) AKOKORO:: Oti oyinbo, egbo agbasa, a o ge egbo


agbasa na, a o da sinu oti pelu egbo ata, didi si
ereke fun iseju marun, lehin na a o tu danu. Odaju.

(d) Ewe agogo igun,omi oronmbo we we,kanwun bilala die,AO bo ewe yen no inu aaro tiwon
ndano,aofun omire SINU ike kan,yioje Dede omi agogo gun yen,aotunbu oti sini odiwon
re,aomaa disi enu.

(e) Akokoro special:


Alomu dudu die,ataijosi,ataale,orin ata,egbo inabiri,ESO boooni,kanafuru,AO gun won diedie
aoko SINU igo AO to oti ogogoro sii,AO maaa di senu.
(f) OGUN DIDUN Akokoro.......
Itakun senifiran, ao gun peepe ninu odo tabi olo ao ko senu, ao ma je lenu diedie, ao di ito re
senu bi 15mins, ti aba si le run bi eni je pako kose nkankan, ti Eeyan ba nrun ni pako lemeji
losu, Eyin re koni yo laelae botiwu ko darugbo to....... But, ao gbodo ma SEPE ti aba nlo ooo

(21) JEDIJEDI
IDANILEKO RANPE NIPA JEDIJEDI/IROBO BY DR. AGBARA
JEDI-JEDI
Jedi-jedi je arun kan,Aisan lao ba pe sugbon kiise nkan ti o ma nsaba da omo eyan gunle loje ki npe
ni aarun.
Jedi Jedi ni isipo pada awon eyan ara ti o se alabagbe ni isale ikun Mon ibi furo iyagbe omo eniyan,ti
awon eya ara wonyi ba di eje sinu ti o si wu koja bi o se ye lo iyen ni egbe duro WA. Ti awon nkan
wonyi Ba wu pelu wipe won di eje sinu ohun lo ma n di nkan ti yio ma da inu lamun ti yio WA ma
mun apeere Jedi wafun eniti nkan bee Ba NSE.
Ni ede kukuru, ima se isekise awon eya ara ti won nba irikerindo ounje sise (excretory system) ni
won npe ni Jedi. Iyen ti won o Ba wa bi o se ye kiwon wa.
Arun yi je okan Lara awon arun igbalode/gbajumo ti o wopo ni ita niseyi ti awon oloyinbo o si fi
bee se awari Ogun ti a le fi koju re ayafi awon baba wa Nile Yoruba.

ORISI ONA TI ARUN JEDI PIN SI.


Orisi meji gbogi ni arun jedi-jedi yii pinsi. Eyiti akoko nje 1. Jedi inu (internal).ti ekeji si nje 2.Jedi
Ita/Irobo (external).

1. JEDI INU:- eleyi je eyiti o wopo pupo ni awujo ti o ma nse eyan ninu ara,leyi o jepe eniti onse o ni
ni anfaani lati fura Mon pelu peki o ri soju tabi ki o gburo re. Opolopo o ki nma wipe ohun ni arun
yi nitori wipe ko mun irora tabi inira kankan lowo. Apeere kan ti o ma ntete ntu asiri eleyi ni ki a se
alabapade eje ninu iyagbe wa.

2. JEDI ITA/IROBO:- Nigbati aye ba gba Jedi inu ti o dagba Dada ti o fi di wipe onjade ninu furo
eni,nugbayi lomawa dipe ao fi oju ara wa ri,ao si mo Lara. Eyi dabi igbati eran Ba su papo ti o po
rekese bi eje bi ibebe furo eni. Eleyi je eyiti o ma nsaba ndunyan Nigbati ao Ba je ko sinmi pelu wipe
ti sokoto wa Ba n nu oju re lo bo leralera, ati Nigbati a Ba fe joko.
A tun le pin ipele eleyi si ona merin ototo,
1. Ipele kini :- ohun ni didan boroboro roboto enu furo.
2. Ipele keji :- eleyi dagba die ju ti alakoko lo,iyato nipe ti a Ba nse igbanse eleyi ma nyoju sita.
3.ipele keta:- eleyi ma nyo nidi eyan ti eyan sile fi ika ti wole pada.
4. Ipele kerin:- ohun ma njade funra re nigbami ti ao si le fi ika lasan ti wole,ipele eleyi ma nfa inira
lowo nitori pe arawa o ni ya gaga si awon eyan pelu ojuti aisan yi ati aiwa Dada WA.

AWON OKUNFA AARUN YII

1. IRUFE OUNJE TI A NJE (diets) :-


ounje ti Anje se Pataki pupo. Opolopo feran ki o ma je ounje sise ti o ti se koja ala,elomo fe le se
ibepe Lori ina koto je ,elomi a koko se (boil) efo (vegetable) ninu omi gbigbona ki o to se lobe. Ti won
o si ki nje awon nkan tutu rara,bi ewe tutu,cabbage, ati bebelo.pelu awon nkan eleso.

2. Ti a Ba ngbe awon eeru to wuwo (lifting of heavy weight), tabi ansise alagbara ju
nigbagbogbo,eleyi ma nko inira Ba awon irinse ti mo daruko seyin ti yio Munwon ma sise kise ti yio
si pada fa Jedi.

3. Oyun nini (pregnancy) :- pelu bi ayipada se nba inu ati eya ara alaboyun,eleyi na manfa Jedi.
4. Aito awon ororo ti nsara loore (inadequate intake of fluids);- ohun na ma afa.

5. Imo je ounje gika ti kofini si aye fun ounje ti a je lati tete fo si we we (digest) di ohun ti o ma tete se
ara ni anfaani. Ki a si sora fun ima je ororo tutu ni opo igba.

6. Ima sise amarayagaga (exercises) lai mo paro omi ti o jade Lara wa si aye re. Iyen ni wipe ki a
gbiyanju ma mun opolopo omi leyin ise amarayagaga.

7. Ki a sora fun nkan mimun tabi elerindodo ti apoju eroja ti won npeni CAFFEINE Ba WA nibe.

IFURAMO/AMI TI AO FI MAPE A NI JEDI. (SYMPTOMS)

1. ki enu furo nipon ju ti tele lo.

2. Ki a yagbe tan ki a tun ripe igbe tun Ku nikun wa lati ya.

3. Ki enu furo ma hunwa.

4. Ki a ma ya nkan fun fun mo igba WA.

5. Ki duro ma rowa lasiko ti anbiya bukata lowo iyen ti anyagbe lowo.


6. Ki enu furo o pon.

7. Ki a fura pe ebi o ma pawa bi ti tele.


8. Ki o ma rewa saara loopo igba laisise.
9. Igbamiran oju elomi a wu.
Èyí ni àwọn ogún ti ao fi koju rẹ.

(a) OGUN JEDIJEDI


BARA ODIDI KAN,A BE EPO E KURO A YO KORO INU E KURO,EPA IKUN A GE
SIWEWE A KOWON SINU KEGI,A DA HOT SI TOBA DOJO KEJI O DI MIMU,AFI
KAFURA KAN SI.

(b) (Ogun Jedijedi Gidi)


Ao Loja Ewe Ewuro Topo Dada Pelu Ewe Efinrin Topo Dada Aowa Gbo Laifi Omi Si Omi
Tobajade Larare Aoro Sinu Ike Kan Aoko Kafura Petebe Si Ao Mamu Laro Laro Aoni Fi Iyo Si
Awan Ewe Yen Gbo O Aogbo Bẹẹni.

(c) OGUN JEDIJEDI TO DAJU:-


eso awogba, kan-un bilala, osun buke, alomu funfun, alomu dudu, ao lowon papo,ao ma femu lo
lekan lojumo.

(d) AGUNMU JEDIJEDI, INARUN ATI NIMONIA:-


IYERE, ATA IJOSI, EGBO IGI AKOMU, A O GUN PO, A O SA KO GBE DAADAA. LILO
RE:- A O MA FI FOKO MU FUN JEDI JEDI ATI INARUN. A O BU SINU OTI, A O MA MU
NI IGASI KOOKAN LARO ATI LALE FUN NIMONIA.

(e)OGUN JEDIJEDI (IDI YIYO)


Egbo erinmodo, a o ge kekeke, a o se ni agbo, eni ti idi re yo, yoo ma mu ni diedie (idaji glass
cup) ni araaro ki o to jeun ati lale leyin ti o ba jeun tan, ni agbara Olorun idi to yo na yoo wole
pada. O daju

(f) OGUN JEDIJEDI:-


Itanna asunwon egba & oyinbo, egbo isirgun, ata wewe, kannafuru, ede osa, ao sa itanna
asunwon yengbe ao gun papo pelu awon elo toku ao tunsagbe dada ao tungun ao lo sugar mo ao
ma fimuko gbigbona.

(g) ENITI IGBERE SABA MA NLE NIPA AKO JEDIJEDI TABI HAHI RI IGBEYAA

(1) Ki iru enibee mamun ewe ewuro 5 laro kutukutu kio fi omi die gbo ki ogbemun kiwon ma
sebe ni emeta lose ,iru enibe ma gbabe igbe lile ati awon arun ara miran toba tera mon ni lilo

(2) ewe rinrin ,ao ja yio poo ,ao fi omi sinnun komon , ao wa da ewe na senun ao jee ao fomi sin
sohun , pelepele ni igbe iru enibe yio ma wa alafia ade toba teramon ni lílọ.

(h) jedijedi
Ao lo wa ewe efinrin ewe ejinrin ewe ewuro ewe iseketu ewe iyalode funfun ao San dada ao wa
gbo papo dada lai fomi si ao fun dada iwonba omi to ba jade nibe ni ao fi iyo si ao ropo ao gbe
mu.
(i) jedijedi:-
ewe agogo igun, eso were jeje, kaun die ao lopo sinu oti, ao ma mu ni gas kan kan laro.
(j) jedijedi
epo obi edun ao ge kekeke sinu igo kan ao ko werejeje die si ao yin odidi atare kan si ao da
amori okin si ao ma mu laro ati lale...

(k) JEDIJEDI
eso asunrin oyinbo ao wa ko po die ao fe idoti re danu ao lo papo ao ma fi mu ogi gbigbona tabi
kia po tea die ka bu ilaji sibi senu kafi tea ti si ku.

(l) ewe asunwon oyinbo ao fomi die gbo ao ma mu nigbakugba.

(m) eso aworoso die ao bo epo re danu ao wa lo kuna dada ao wa su rodorodo ao wa fi omi osan
wewe lo bi ogun oyinbo ,ao lo ni aro kutu kato jeun ao wa jeko to wakati meta si marun kato je
ounje elepo.

(22) NARUN
(a) (agbo narun)
Egbo sagere,epo oganwo,egbo ogbo,egbo botuje funfun ati pupa,eru,ao se yio mamu

(b) OGUN NARUN:


Opolopo ewe irawole, omunu ewe oronbo, ata atetedaye, ao gun po, ao sa gbe, ao fise agunmun,
mimu pelu eko gbigbona.

(c) Agunmu ako narun

etu ibon ojuda,eso inu ibepe to pon,eru alamo,okunrun(millipede),alakan,a o gun papo,a o mu


lale fun ojo meta,eko gbigbona laro fun ojo mẹta.

(d) AGBO NARUN KI ARA MAJA ENIYAN JE/KI OJU MA SU:

Egbo atapari obuko,epo amuyan,alubosa elewe,enukopire,eru awonka a o fi tele ikoko/ike


olomori a o ko nkan toku lee lori a o bu omi si a o de pa fun ojo meta lehinna a o ma yo mu ni
ilaji cup.OSE RE:Egbo inabiri tutu,ewe laali a o gun papo a o ma bu agbo yen sinu omi iwe a o
maa fi ose yi we.

(e) OGUN NARUN OJU TABI TINU Ara.


aowa ewe rerinkomi tutu aofonu pelu omi aobo gegebi efo aoroje lefo pelu epo pupa iyo egusi
aose be fun odidi ose meji tio ni ja rara, leyin ose meji wafun ile láró.

N:B nigba ti aba bere sini je efo yi agbodo jinna si gbogbo nkan ti wonfi ororo se tabi ororo gan
boya ti kuli tabi omi ti abatun mon tabi epa sise or yiyan, tori ki abiku mon so ologun deke.

(f) OGUN NARUN:-


EGBO IPETA, EGBO GBOGBONISE, INABIRI, KAHUN BILALA DIE, IRU, IYO,
ALUBOSA ELEWE, AO GUN GBOGBO REPO, AOMA FIMU EKO GBIGBONA.

(g) OGUN NARUN


Aidan isirigun fofo olokun tagiri iseta imi ojo egbo ahun egbo inabiri egbo gbogbonse egbo eru,
eru awonka alubosa baka atare iyo kahun Atajosin jankariwo efin
Aogunpo lagunmun aomafi mun eko LARARO.
(h)Asejenarun.
Ewe inobiri aolo pelu iyere aofi se eran tutu je lepo niyo.

(i) Agbo sise fun narun.


Ewe iwarigbo eru awonka aose papo ao ma muun.

(23) STROKE RỌPA-RÒSẸ


IDANILEKO RANPE NÍPA AÍSÁN STROKE. (By Dr. Adetoyi Adekunle)
Siwaju ki n to so oro nipa stroke,emi ni igbagbo wipe gbogbo wa la mo nipa aisan eje riru nitiori
oun gangan ni oga nkan ti o n fa ropa rose,eleyi fi ye mi wipe ti a o ba manage high blood
pressure daadaa,stroke lo ma gbeyin eni na.Ropa rose je aisan,kii se arun rara nitori a ko le ko
ni ibi Kankan ayafi ti a ba jogun awon nkan to le fa,aisan yi ti po ni ode isaluaye debi wipe
akosile ti so fun wa wipe opolopo awon eeyan lo ti ipase re lo si orun. awon eyan tun so wipe
jejere(cancer) na tun pa eeyan sugbon opolopo ni awon ti jejere n da lamu ti won tun ni eje riru
leyi ti o ma n fa ropa rose,elomiran a si tun ma ni ropa rose pelu jejere,ki olohun wole asiko
yi,arunkarun abi aisan ki aisan,ko ni je tiwa.

Ropa rose ni aisan kan ti o ma n wa ye nigbati lilo bibo eje ninu isan ara ba pakaso lati
de inu opolo(brain) omo eda eniyan.eleyi si le waye ni orisirisi ona,fun apeere,ti eje ko ba ti ri
aaye lati de ibi ti opolo wa,eleyi ni o ma fa ki awon eya ara ti opolo na se alakoso re da ise
sile,nigba na ni a ma n ri wipe apa ti ro,ese ti ro,enu ti wo,ahon ti lo ati bebelo.
Aisan yi tun le fa ki eeyan ma ranti nkankan mo,awon isan ara na ma n da ise sile.ibiti
isoro ba rolu ninu opolo lo ma so iru nkan ti yio ma se alaisan na,fun apeere,ti o ba se wipe
kekere ni apa ibiti opolo na ti ni arolu ni,opolopo iru eeyan be ma n saba gbadun sugbon ti arolu
opolo yen ba po,o seese ki eni na ma dide mo lailai.bakan na ti aisan yi ba rolu eeyan,opolopo
igba ti o ba rolu apa osi ni o ma n fa iku nitori ibe ni okan wa,eleyi yio si fa idiwo fun okan ati
opolo lati ma sise ni asiko kanna.
Aisan opolo ni roparose je,ti o ba ti n ba opolopo aaye nibi opolo ja,iru won ni owo abi
ese won ma n gan pa ti ahon won na ma lo nitori eje dudu ti gba akoso aaye yen niyen.kosi eniti
aisan yi ko le mu yala arugbo abi omo kekere,eeyan si le jogun lati odo awon obi re.aisan ropa
rose je aisan ti o ma pa eniti o ba mu nitori re ni awon oyinbo fi pe ni TERMINAL
DISEASE.eeyan le dabo bo ara re ko ma ba ni aisan roparose yi.ni igba kan,aisan awon olowo
ni sugbon ni asiko yi,kosi eniti ko le ni aisan na,aisan yi le je afowofa,o si le je asasi/abilu.mo fi
asiko yi be olohun fun gbogbo wa wipe a o ni aisan lo igba lase edumare.

e je ki a wo orisirisi ona ti aisan ropa rose ma n gba mu omo eeyan,eleyi lo ma so orisirisi(type)


aisan ropa rose ti o wa ni Nigeria
orisi meji pere ni aisan yi pin si,alakoko ni won n pe ni
i. hemorrhagic,
ii. elekeji ni ischemic.
labe orisi mejeeji yi ni awon eyiti a ba tun mo ti jade
i. HEMORRHAGIC STROKE
eleyi ma n sele ti awon isan(blood vessels or arteries) ti o ma n gbe eje lo sinu opolo ba da ise
sile.eyi tumo si wipe ti o ba ti re isan,yio ma sun ki,eleyi ko ni je ki eje ti o to de ibi ti opolo
wa,latari aito eje ninu opolo,akitiyan ti opolo n se ma din ku.Bakanna,eje ti o ye ki o kuro nibi
opolo pada si inu okan ko ni le jade,eleyi ma fa ki eje na di(clot) si ibi opolo na.nkan ti o ma n fa
ki isan ma lagbara lati gbe eje lo sinu opolo ni eje riru ti a o se itoju re daadaa.opolopo eeyan ni
Nigeria ni o ko adanwo stroke latara nkan bayi,mo fe ki awa onisegun kiyesi eleyi.oro po nibe
gan.iru eya aisan ropa rose yi na pin si ona meji;
i. INTRACEBERAL HEMORRHAGIC STROKE,

II.SUBARACHNOID HEMORRHAGIC STROKE.

 *INTRACEBERAL HEMORRHAGIC STROKE-


Ti awon isan ti o gbe eje kuro(veins/blood vessels) lati inu opolo ba da ise sile,eje ti o ye ki o
pada sinu okan ma di tabi ki isan yen gan be(burst),latara bayi,eje yio wo inu opolo,eleyi ma fa
abawon fun opolo,latara nkan bayi,wahala lati inu opolo yio bere nitori opolo yen yio ma se ise
lile(pressure will increase within the brain and as a result,damage the brain cells).
Rire(body weakness while coming from bed), aile jeun daadaa(trouble swallowing),
oju a ma se bayi bayi(blurred vision), ooyi nigbakugba(loss of balance &
coordination,dizziness),loss of memory,sleeplessness,confusion/indecision making,sometimes
vomiting,ori fifo ni gbogbo igba ni akoko wahala,a o wa ma lo paracetamol ati alabunkun leyin
to je wipe o ma da kun wahala yen,eleyi si le ja si iku lojo na.eniti iru aisan yi ba mu,ko ni mo
nkankan mo,ko ni da eeyan mo,ti o ba je GENIUS,walai,the brain retention will wipe off.brain
tumor,sickle cell anaemia,eje riru ti a o toju lo ma n fa eleyi,o si wo po daadaa ni Nigeria.ni ilu
oyinbo,ise abe ni won ma n se,won n se ise abe na ni UCH Ibadan sugbon opolopo pada ma n ku
ni.
a le dabo bo ara wa ki a ma ba ni eya aisan yi,
 avoid smoking.
 treat all heart disease
 manage your blood pressure
 keep diabetes under control
 engage in physical and simple exercise
 maintain a healthy lifestyle etc

 SUBARACHNOID HEMORRHAGIC STROKE-


Iru eleyi ko wopo.nkan to ma n fa ni tie je ba n sun ni agbegbe opolo(bleeding on the surface
of the brain).kosi amin Kankan ti o le fi han eniti aisan yi mu ti yio fi mo wipe nkan be ti n
sele si oun sugbon o le sele ti eeyan ba se ise ti o ju agbara eeyan lo(physical effort/straining
of muscle) gegebi iko awule,igbe gbuuru,gbigbe nkan ti o ju eegun wa lo(lifting something
heavier),obo/oko dido ni gbogbo igba(extreme intercourse) ati bebelo.
Ni ojo ti aisan yi ba farahan,apeere ti eeyan ma ri ni efori to le gan ti yio da bi igba ti
won ba fo irin mo eeyan lori(a sudden agonizing headache that will seems someone is being
hit by an iron rod),loju ese na ni ayipada yio bere si de.
iru ropa rose yi nilo ayewo papapa(the brain need to be scanned to know where the
problem lies).kosi nkan pato ti o le fa iru ropa rose yi sugbon eeyan ni lati dena
 siga mimu
 oti amupara
 eje riru
 lilo ogun oloro abi ilokulo ogun(taking overdose drugs).
a o ni fi aisan lo gba,a o si ni fi ojo olojo lo.

 ISCHEMIC STROKE
Eleyi le waye ti eje(blood) ba di(blood clotting),ti eje ba wa di ninu isan ara omo eniyan,lilo
bibo eje ma pakaso,latara eleyi,eje ko ni le ibi opolo,eleyi ma n saba bere lati ibi
arunmolegun,pajapaja,ki owo abi ese ma ku riri, ati bebelo.
Ti omo eda eniyan ba wa ni Alafia,eje re ko gbodo di ni ibikibi yala ninu okan(heart),opolo
abi ninu isan.ifunpa giga ni gbogbo igba lo fa eleyi na.iru aisan ropa rose yi na pin si orisi
meji;alakoko ni EMBOLIC STROKE ti elekeji si n je THROMBOTIC STROKE.

 EMBOLIC ISCHEMIC STROKE


Iru aisan ropa rose yi ma n waye tie je omo eeyan ba di(clot) ninu isan ti o si gbe irufe eje be de
inu opolo,eje didi na ma duro si ibi opolo leyi ti ko ni anfani fun eje lati de ibi ti opolo wa,latara
bayi,opolo yio da ise sile,aisan ropa rose ma de.
Eje didi le waye ni ibikibi ninu ara,yala ese,apa,idi,orun,aya ati bebelo sugbon eje didi
yi ma n wa lati inu okan ni.eleyi tun le fa ki eeyan ma mi gulegule(a condition in which the heart
does not beat effectively,causing blood to pool and clot).
Irufe ropa rose yin a le gba emi lojiji,awon arugbo,ifunpa giga,high cholesterol,ito
sugar,ome autoimmune diseases,smoking,obesity,alcohol and drug abuse,ajogunba etc ni awon
ti o ma n saba ko agbako aisan yi.eniti o ba ni aisan ikan gbodo toju re daadaa.

 THROMBOTIC ISCHEMIC STROKE


Irufe aisan yi ma fa ki eje di sinu opolo gangan.ti eje yi ba ti di,apa ibiti arolu yi ti sele yio da ise
sile nitori eje tuntun ko ni le de ibe mo,eleyi ma fa ki brain cell yen ku lojiji.awon nkan ti o le fa
iru aisan yi ni ajogunba(hereditary),ito sugar,eje riru,apoju ora lara,siga imukumu.awon apeere
ti eeyan ma ri ni ti aisan yi ba n bo,efori gbogbo igba,ooyi,ara riro gbogbo igba la I sise
agbara,ki ara ma kuriri,ki ahon ma ro po ati bebelo.

NOTE;transient ischemic attack is mini stroke but in my own case,it is a warning to the
patient.sometimes,it can happen and within 30minutes,it disappears with or without
medication.eniti o ba ni iru iriri yi gbodo kiyesi ara daadaa ki o si se itoju to peye lori ero ati idena
ropa Rose.

Aisan ropa rose lati owo awon agbalagba


Ni ile Yoruba,ko si aisan abi aarun ti won ki fi se eeyan,yala ito sugar,jejere,ropa rose,airi omo
bi,iba eyikeyi ati bebelo.eje ki a ma se etutu daadaa fun awon alaisan ati fun arawa ki a ma ba
fori ko egun elomiran.eyi ni ma fi gba gbogbo wa ni imoran wipe ki a ko arawa ni awon ogun
ero lorisirisi,ogun idena awon aarun lorisirisi leyi ti yio ma je ajesara nitori awon agbalagba ojo
si,gbogbo nkan ti o ma n pa eeyan ni won dan wo sugbon won tun dagba ki iku to pa won ni,e je
ki awa na ko arawa ni ogbon agba ati ogba igba iwase,koni baje o.aisan ko ni fi ara wa se ibugbe
ó.

Lara nkan ti eniti o ba ni aisan ropa rose gbodo mo ni wipe


 -ki a ma se exercise deedee
 ki a ma je garlic
 -ki a ma se mu oti
 -ki a ma se mu siga
 -ki a ma lo oogun oloro
 -ki a ma se lo adieyan
 -ki a ma se je awon ounje ti o ni ora(fat/cholesterol) abi ororo ninu paapaa awon ounje
fast foods
 -ki a ma se ma mu nkan tutu bi omi abi soft drinks
 -ki a si ma fi omi gbigbona we
 -bi o ba se n se wa,ki a lo ma ri dokita
 -aisan alore ni ropa rose,eje ki a ma gba owo diedie.

(a) ogun stroke :


Ewe taba gidi yio po,itakun ako ibepe,a o re wewe a o ko tele ape a o ko ewe taba yen le Lori ao
fi omi se ni agbo yio ma fi we.

(b) Ọ̀sẹ̀ re: igbe Malu,igbe elede,igbe aguntan a o lo po a o sa GBE lorun ao po mo ose yio fi ma
we agbo yi

(c) Aseje re:: ewe odan,itakun re to oma nsan wole lara igi re yen a o ge a o lopo a o fi se eran
aguntan je fun emi na.

(d) AGBO STROKE:


EGBO ITO IGBIN,TEWETEGBO ASASA,EWE OPARUN,ORI AMU,A O SE LAGBO.OSE
RE:WEREPE TI OMA NSIBO SILE LARA OPARUN,EWE AROJOKU,ODINDI ATARE
KAN A O JO PAPO A O PO LOSE DUDU,A O MA FI WE AGBO YEN NI GBIGBONA.YIO
MAA MU NINU RE PELU.
(e) ASINPA STROKE:
AKEREKERE MEJE,ASE OKA MEJE,EWE ESINSIN,OKO ATARE KAN,A O LO WON
PAPO,A O FI SIN AGBELEBU SORI ENI NAA,A O TUN FI SIN APA ATI ESE TI O RO
PELU.A LE SIN GBENREN YI TO EMETA/EMERIN,A O DA DIE SINU SCHNAPPS A O MA
FUN ENI NAA MU NI AARO ATI ALE.GBOGBO WA KONI FI AISAN LOGBA Ó.

(f) STROKE
ewe ogede agbagba to gbe dada to resile funrare ao lo kunna aoda sinu adi dudu ao ro omi igbin
meta sinu e, fun ipara aofi ma gbogbo ara ao ma ro omi igbin sinu gas ori schinap aoma mu iyen
ti aba fi adin yen para tan..

(g) Ki stroke male muwa:


_a o lo egusi itoo,a o fi ewe imi esu se efo pelu eran malu ekiri merin lepo niyo sugbon ko si ata
nibe ó.

(h) Ki stroke male muwa:_


ewe ejinrin tutu a o lo po mo ata ijosi ,a o fi se igbin topinu kan je lepo niyo.

(i) ERO STROKE.


Pandoro kan, aogun, aofun omi inu re sinu igo kan, aowa oyin igan toje dede omi pandoro yen,
aomix mejeji papo, aowa fi kanhun bilala die si, aotun mix re dada, eni naa yio mamu gaasi
kookan laro ati lale titi yio fi lo. Olohun koni fi aare sewa ooo ati gbogbo ebi wa.
(j) Ero stroke/ajesara fun asasi-
a o fi ose dudu yi gbogbo ara opolo aaye kan,a o Jo pelu odidi atare kan,a o fi gbere meta meta
si orikerike ara,a o ma fi iyoku fo eko mú.

(k) AJESARA STROKE:-


imin Ojo Dudu{somisoro},epo Obo Die,eyo Atare Mejo,ao Gun Papo Ao Fisin Gbere Kookan Si
Orikerike Ara.Bi Otiwun Ki Eniyan OSE are to Stroke Konimu Eniyan, Isha Allah.

(m) AGBO TUTU FUN STROKE


EGBO OSUNSUN,EGBO AGBASA,EGBO EJINRIN,EGBO WOWO,EGBO ENU
OPIRI,EGBO EWU OKO,EGBO EWURO JIJE,EGBO AKO IBEPE,ISU AKITI,EGBO
GBOGBONSE,EGBO ARINGO,EGBO GBOGBONSE,EGBO IPETA,EGBO IYERE,EGBO
AGUNMONA,EGBO KOLEOROGBA,EGBO IFON,EGBO TUDE,EGBO KAKO,EGBO
EWURO IJEBU,EPO OGANO,EGBO KAKANSELA,EGBO EWON AGOGO,ESO
TANGIRI,EGBO OKAN,ISU OGEDE ODO DIE,AKUKO ADIE KAN,A O KI GBOGBO RE
LAGBO PELU OMI SINU IKOKO ORU,A O PA ADIE YEN,A O FI EJE RE BO ARA IKOKO
YI,A O FI ADIE NA SE ETUTU FU AWON TO N SE AKOSO AYE

(n) AGUNMU FUN STROKE


EGBO ORUWO,EGBO WOWO,EGBO INABIRI,EGBO IPETA,EGBO ASUNHAN
YORUBA,EPO AMUYAN,EGBO OROMBO WEWE,EGBO JAGANYIN,EGBO TUDE,ISU
GBEGBE,EGBO GBOGBONSE,EGBO ERUJU,BAKA,AKO KANHUN,ATA WEWE DUDU
ATI PUPA,IYO,ALUBOSA ELEWE ATI ONISU 10,ODIDI ATARE 10,OROGBO10,OGEDE
OMINI DUDU 10,OGEDE AGBAGBA DUDU 10,FOFO OKUN 10,AIDAN 10,FIRIGANMU,A
O GUN NI AGUNMU,A O MA FI MU EKO GBIGBONA.

(o) AGBO SISE FUN STROKE


EPO OGANO,EGBO IROKO,EGBO TUDE,EGBO IFON,EGBO ORUWO,,EGBO EWON
AGOGO,ISUMERI,EWE ESUN PUPA,A O MU AKUKO ADIE KAN FUN ALAISAN YI,A O
NI KI O DURO SINU OORUN,A O NI KI O LA ADIE MO OJIJI(shade) RE NI EKAN SOSO
TI YIO SI KU, A O FI ADIE NA TELE IKOKO,A O WA KO GBOGBO EGBOGI YOKU LE
LORI,A O BU OMI SI,A O SE LORI INA,YIO MA MU DIEDIE,YIO SI MA FI WE.TI
EEYAN BA MU,O SESE KI O MA BI,E MA BERU,SUGBON DIE I SIBI META NI KI O MA
Mu.

(24) ÌTÓ SUGAR (DIABETICS)

IDANILEKO
BY
(DR. ADEBAYO TESLEEM KAYODE)
SHC GRAND PATRON

( Topic) " Ounje towa fun eni ti aisan ito sugar( Diabetes) nda laamu",

( Diabetic diets).

Fun agboye akole yii, kin lode ti aose ayewo oun ti anpe ni ito sugar nipato.
Eleyi ni o muwa losi ipele akoko tianpe ni
INTRODUCTION...
Ito sugar je aisan kan tonise pelu opo ( high) sugar ninu eje wa. Kinlo jekio ribe? Aisimo ( lack)
abi aisito ( insufficient) Ororo INSULIN ti eya ara inu ara tianpe ni PANCREAS nsun
( produce). Eyan amojogun aisan yii ( hereditary) abi kio muyan gege bi aisan yoku. Beeni aisan
yii pin si ona meji.
 Type 1..... Insulin depedent , tojepe kii saba gbo iwosan rara ti alare naa yio mo gba
abere insulin lo titi laelae and
 type 2.…..non- insulin dependent toje wipe alare naa le pada ri iwosan latara orisirisi
itoju..........APERE ti aomari tiafin mo eni toni aisan ito sugar ni yii........ito tito tiyio
poju (excessive urine), oungbe pipoju ( excessive thirsty), riru tabi gbigbe ( weight loss),
ebi pipa ni gbogbo igba (hunger), skin problem, oju wiwo bulabula ( blurred vision) ati
bebelo.

Ona po lorisirisi tiangba toju aisan ito sugar sugbon ejekia mu enu badie nibe.
Akoko nibe ni OUNJE JIJE ( diabetic diet).
Eleyi je igbese akoko fun itoju ito sugar. Biko bagbo, aolosi igbese keji tianpe ni ORAL
treatmemt. Eleyi nise pelu lilo oogun lorisirisi ( e.g methformin, daolin, diabetmin e.t.c) latifi
koju aisan yii, bi aisan bako tiko gbo igbese keta ni gbigba abere INSULIN lorekore. Eyi totun
gbajumo ninu re tosi dara pupo ju ni EXERCISE.........

DIABETIC DIETS (ounje towa fun eni toni ito sugar)..

Eleyi gan ni akole wa dalori. Imo ijinle fiyewa pe nipase ounje topeye, ale toju tabi dena aisan
ito sugar. Akoko, jije FRUITS and VEGETABLE. Fruits bi water melon, cucumber , ibepe,
strawberry lodaraju toriwipe iwonba ni sugar towa ninu won. Other fruits bi orange,
pineapple, vegetable like efo ewuro, efo tete e.t.c naa dara.

(2) Tiaba nsoro nipa ounje okele ( swalow), Wheat and unriped plantain based foods lodara ju
awon iyoku lo. Toripe starch( carbohydrate) tiwon ni kere pupo si awon ounje iyoku bi
eba ,amala, iyan e.t.c. Yato si eleyi, wheat and unriped plantain flours ni LOW GLYCEMIC
INDEX. lehin digestion, diedie ni glucose toba produce nwonu ara wa tiyio si se ara la nfani.

(3) PROTEINOUS FOODS.....awon ounje tinmu ni dagba bi eyin( eggs), ewa ( beans), wara
( cheese), milk ati bebelo lodaraju fun eni toni itoju sugar toripe won kii se akoba fun ara beeni
won si nse ara loore.
AWON OUNJE TIKO DARA FUN ENI TONI ITO SUGAR

 (1) Oti ( alcohol)


 (2) awon onje toni ororo pupo ju ( fatty foods),
 (3) starchy food e.g bi eba, amala, iyan, fufu ati bebe loo.
 (4) processed food.......e.g processed meat,
 (5) soft drinks.......coke,fanta, 7up e.t.c.

Conclusively, gbogbo ounje toje eewo tiaka kale pata ni eni toni ito sugar leje sugbon koje ni
wonba including eba, fufu, iyan. Ikuku ( fist) olukaluku eni toni aisan yii niyio juwe dede ( size)
onje tio maje. Owa leje bee lemefa lojumo. Long life S.H.C !!! Abomi koju bayi lo. !

(a) OGUN ITO SUGAR


Esururu pupa ama jo mo odidi atare kan oti sinabu ni ama fi lo lara ati lale.

(b) AGBO ITO SUGAR:


EGBO EWURO,TEWETIGI ISEPE AGBE,EPO PANDORO,EPO ORIN DUDU,AO SE PAPO
MIMU LAARO LALE.

(c) (OGUN ITO SUGAR)


Omi Osan Wewe Topo Ewe Efinrin Ewe Ewuro Ati Abere Die Aofi Omi Osan Yi Gbo Awan Ewe
Yi Dada Aowa Lo Abere Yen Aoda Si Aoro Gbogbo Re Sinu Ike Kan Ao Mamu Ni Gasi Kan
Laro Laro Odaju Edan Wò.

(d) Ito sugar,ewe efirin a o gbo papo pelu ewe ewuro.a o yo omiri se,a o papo mo omi osan
wewe,mimu diedie,same measurement ni yio je ó.

(e) Agbo ito sugar


epo oganho , epo afon , epo amuje , epo aku / oori , epo ira , epo iyeye , epo agbon , epo koko
abalaye , epo opoto , poroporo oka baba die a o fi omi ogi se tabi kia ba eru ki a fi se . Aisan o ni
file wa se iso amin o .

(f) ITO SUGAR


aoko iru woro tele ikoko agbo ao wa ja ewe ewuro bo mole so wa da omi si ao see kio jina, fun
mimun ni.
(g) OGUN ITO SUGAR(DIABETICS)
--ao wa esuru funfun tutu, ao be eepo ara re kuro, ao gesi si wewe, ao re sinu omi tutu, ao mamu
idaji cup lemeta lojumo.

(h) OGUN ITO SUGAR


:Bara nla kan,a o ri mole fun ojo meje/mesan,a o lo wu a o be epo ara re kuro,a o yo egusi inu re
danu,A o lo abeere die,a o da sinu ike olomori kan,a o fi kaun bilala sii,a o ge bara yen sinu re a
o wa da omi osan wewe lee lori,a o de pa fun ojo meta,lehinna ilji Cup laaro lale.Ki eni naa lo se
ayewo lehin ose kan.2:Ewe kankan ayaba,a o fi BIG STOUT gbo daadaa,ao se a o ro sinu ike
EVA,a o ge alubosa aayu kekeke sinu re,eninaa yio maa ni ojo keji pelu ilaji CUP laaro lale.
(25) ULCER OGBE INU

(a) Iwosan ulcer tio daju(ogbe inu)


A o wa ewe ireke oge.(Ireke obo)a o wa ewe ogede omini naa.a o wa ori amo.(Sea
buter)topo die.a o fi ori amo yi se ewe mejeji yi papo tio ba ti jinan,kio to tutu a o ma
fi sibi imuko mu diedie,tio ba ti tutu a o tun gbedi ojomiran kia tun gbe kanan kia
tun mu titi a o fi mutan.

(b) Ogun ogbe'nu todaju


Ao Lowa Osan Agbalumo Topo Dada Ao Wa Odindi Atare Kan Ao fijo Papo, Ao Mafi
Foko Mu.

(c) OGBE INU ULCER


Ikun igi agan o, ewe arojoku, odidi atare kan, jijo po, to sinu epo pupa lila laaro ati lale.

(d) OGBE INU ULCER


OGEDE AGBAGBA DUDU AO RE TEPOTEPO AO DA SINU IKE 2LITERS AO DA OYIN GIDI
SI AO JEKO TORO DADA AOMAMU ARO ATI ALE .

(e) Ogun Fun Ogbe inu


Ao lo ja ewe gbeere tan pe ni jaloke, Ao ja ewe na ao se ni agbo fun mimu.Idaji koobu
(Cup) ni ao mu kato jeun...

(f) Ki a fi iyo die gbo efo gbure (water leaf), Ao ma mu ni aro kato jeun.

(g) OGUN OGBE INU


Gbogbo ifun inu adie akuko tabi abo, tabi ifun inu mejeji ao jo po ao da sinu adin ao
ma la.

(h) Ewe ewon ao lo pelu ihere ao fi eja aro se to ma po ao ma je diedie.


(h) Agbo ogbe inu (ulcer)
Ao wa omundun ewe igba tiwon fi nse iru kopo dada, kanhun bilala die, aose lagbo
lorina tio jinna dada aowa mon yomu lemeta lojojumon hmmmm leyin ose meji walahi
wadupe fun olohun tofi tewe tegbo mon awon Baba wa.
(i) OGUN OGBE INU
Ao wa ogede agbagba to pon dada ao bo epo ara re ao ge kekeke ao ko sinu abo kan ao
bu omi si ao ma mun ni aro kato jẹun.

(j) Fun ogbe inu(ulcer):


eye obe kan,atare kan a o jo po,a o pin si ona mefa,a o fi omi lo fun ojo mefa.

(k) OGUN OGBE INU (ULCER)


KUKU AGBADO ORI AKITAN LOPOLOPO,A O DA SINU APE,A O DA OPOLOPO
IYERE ATI ODIWON ATARE LEE LORI,A O JO PAPO,A O MA FI FO EKO MU.

26. ALEKO MAN POWER


(a) ALEKO/ALERA PATAKI.
ori ejo agbadu, ewe ekuku, ao lọ po, pelu sugar, aodasinu oyin, ao má laa.

(b) (OGUN ALEKO)


Egbo Aidonu Toro Egbo Igi Okete, Eruju, Madunmaro, Opon Egbo Idin Aore Pelu Oti
Sinu Kegi Kan Aowa Fo Eyin Adie 3 Si Aowa Da Milk Alagolo Meji Si Aofi Iso (nail 6)
Sinu Re Ao Mamu Leyin Ojo Keta Nigba Toba Wuwa.

(c) OGUN ALEKO ATI MOKOGUN:


Oko ese,egbo aidan toro,egbo gboingboin,alubosa elewe,eye adan gbugbekan,a o ge ewe
ogan to yowo jana sinu re,a o gun won papo,a o po mo ose dudu,a o po die mo oti a o ma
mu diedie,a o ma fi ose toku fo oko si isale.

(d) ALEKO
Abere topo ao lo loto egbo tude gbigbe ao lo loto ao bu diedie ninu mejeji ao da papo
sinu ragolis ao bu omi si so mamu leyin ojo kẹta.

(e) OGUN ALEKO.


Egbo ogbolo, Eso iyan(Pandoro lon jebe), ao re si we wewe, ao ko sinu agbada ao Jo
papo,
Ti abafe lo, ao ko sugar onipali sinu e, ki o dun daada, bi ebu naa base poto ni ao fi lo
sugar mon, ao ro sinu igo nitori koma baa tutu, ao ma la niwonba sibi kekere kan, nigba
gbogbo.... Odaju.

(f) Egbo sagere,egbo sapo,egbo inabiri,egbo akogun,egbo aidan toro,epa ikun,egbo


ogbolo funfun ati pupa,a o fi oti ki,a o ma mu lati ojo kẹta.

(g) OGUN ALE GBANGBA


EWEPALE ORUN AKUKO ADIYE TOGBO DADA OGEDE AGBAGBA DUDU
AOGUN PO MO OSE AOFI ESO KAN OSE NAMO ARA OGIRI AOMAFI FO BABA
ISALE WA.

(h) ONI GBEREN ALE


OKO ATARE KAN ORO IDI AKEKE AOLO AOFI SIN GBEREN YIPO IBADI.

(i) EGBO OSUNSUN EGBO AIKA EGBO IDIAPATA EGBO IGI ATA EGBO
ATAPARI OBUKO EGBO AKO IBEPE EGBO IGO ERU AWONKA TIKO KAN
RARA EMU OGIDI LAOFI SE AOMA MU.
(j) OGEDE AGBAAGBA DUDU,E O NI BO EEPO ARA RE,EO GBE SINA,BO BA SE
NJO DIE DIE NI E O MA HA ARA E,TITI O MA FI TAN,AO LO ABERE META
PELU EEDU YEN AO DA SINU OYIN GIDI AO MA LA,TO BA JE ISE PAAPAA NI E
FE KO SE E DA SINU OGOGORO TI WON FI EMU SE,TI O BA KU BI OGBON
ISEJU TI E MA WOSE E MU.

(k) OGUN ALEKO PATAKI


orogbo, obi gbanja,etu ibon, ako okuta, ogede agbagba tiko pon, esuru ff, gbaguda ti
won fi n gun iyan je, iyere, agbado, sugar die ao gun gbogbo re po ao mafi foko mú.

(l) Ogun Aleko


Ori ejo sebe kan,Ori Alabahun kan, Odidi Atare kan,Ao jo papa. Ao wa lo papo mo etu
ibon gidi... Ao ma fi fo eko tutu mu...
(27) OYI (GIDDINESS/DIZZINESS)
(a) OYI OJU.
egbo ibepe, eso isin, kanhun, ose dudu, epo isu ti abe kuro lara isu, eru awanka, aoda
lagbo pelu omi tutu, aose, yiomamu ni emeta lojuma.

(b) OYI OJU, OYI INU ATI OYI ORI (ALL IN 1)


Ao fi odindi atare kan tele ape, ao fi ori lambe le lori, ao wa ko opolopo itanna pandoro
lee lori, ao wa jo papo. ao ma fi foko tutu mu. tabi omi tutu. gbogbo oyi patapata loko.

(c) OGUN OYI OJU


A O LOWA ESO OGURO KI O PO DIE, A O WA KO WON SINU INA, TI OBA TI JO
DADA, A O KOSI OJU OLO, A O WA YIN OPOLOPO OMO ATARE SINUE, A O LO
WON PO, A O MAFI MU EKO TUTU TABI OMI TUTU.

(d) OYI-OJU ALABOYUN


Ori ako-olube, epo igi agbon, epo igi apa, odindi atare kan, ao jo papo. Odi lila fun
alaboyun na die-die.

(e) OGUN OYI OJU


Ori eiyele kan ewe epiya atare odidi kan ao jo po ao ma fi foko mu fun eni ti oni oyin.

(f) OYI OJU


EPO AWUSA, ORI EYE ETU, EWE ALUPAIDA, OTA INU IROKO, ODIDI ATARE
KAN, AO JOPO, AO DA SINU EPO PUPA FUN LILA.

(g) OGUN OYI TODAJU


EPO AWUSA,ORI EYE ETU,EWE ALUPAIDA,OTA INU IROKO,ODIDI ATARE
KAN,AO JO PAPO,SO DA SINU EPO PUPA,AO MA LA.

(h) OGUN OYI


IGBA AYA ALABAWUN,ODIDI ATARE KAN,AO JO PAPO,AO MA FI LO EKO
GBIGBONA.
(i) ELEYI NI OGUN OYI OJU ATI OYI ORI

ESO OGAN LEGUN PUPA ILE ADIRO TIKO ITIKANLE EPO ARA OPE
TOWOLULE FUN RA RE HORO INU OWU OTUTU ODINDI ATARE AOJOPO
AOMA BUSINU OGERE EPO FUN LILA ABARA MU O.

(j) OGUN OYI

OPOLOPO ESO IYEYE,ODINDI ATARE KAN A O JO PAPO,A O MA FI OMI LOO

(28) ABIWERE
(A) ABIWERE.
Ipe aaka,ipe oore,eyin ti o bo sile funrare,odidi atare kan,ao Jo po,ao po mo ose dudu, ti
obinrin ba ti wa ni OSU re yio FIwe pelu gbolohun yii.
Ofo:- tipetipe laka nbimo tie
tipetipe loore nbimo tie
ojo tara bade eyin nibo Lori Iya re
Ti asiko ba to ki ara o de emi LAGBAJA omo lagbaja ki ara o demi ki mbi were
ooo.. Yio wa fi ose naa we.

(b) OGUN ABIWERE FUN OBINRIN


EWE EJINRIN, A O GBO PELU OSE DUDU DIE, KI OBINRIN NA MU NI IGASI
KAN TABI MEJI, YIO BI NI WERE PELU ASE Ọlọ́run.

(c) ose abiwere


ipepe aka,ipepe ore,imin ewure,imin agutan, to babi mo ri,eso afon, ao fi odidi atare kan
si ao jopo ao ro sinu ato
OFO re:.Tipe tipe lakabi,tipe tipe lorebi,enikeni ki gbebi ewure,enikeni ki gbebi agutan,
tipe tipe lakabi,tipe tipe lorebi,enikeni ki gbebi ewure ati ibi ati ire lafon wo, oso ile,aje
ile ki o mon mo igbati lagbaja yio bi omo tire o.. ao po die mose yio mafi yoku fo eko
tutu mun.
(d) KIWON MALE SISE ABE FUN ALABOYUN
AKO IRE META ABO IRE MEJI ODIDI ATARE KAN AOJO PO ALABOYUN NA
YIO FO EKO TUTU MU LATI BI OSU MEJE SIWAJU PELU OGO OLORUN LAYO
LOBINRIN NA SO.

(29) ORÍ FIFO

(a) ERO EFORI.


Ekuro 7.etu ibon, eyo atare 7,aolopo, gbere 6 ni ipako ati ni waju ori. odaju.

(b) OSE GBOGBONSE FUN: TITA,GIRI,EYII,EFORI/TUULU:


A o ha gbogbo ara tagiiri,isu lugborogan,ewe ewuro,a o gun won papo mo ose,a o po
ogogoro ojuda mo a o ko sinu igo olomori.

LILORE:A o po die mo oti ,a o maa mu ni gaasi kan laaro,losan ati lale.Fun TUULU A o
maa fi fo ori sinu BASIA tabi ike nla kan,a o lo da si ita gbangba.

(c) EFORI TULU,-


AO GUN EWE EJINRIN ATI ERU MON OSE,AO LO FI FO ORI NAA SI
ORITAMETA,ODAJU

(d) EFORI TULU -KODA KOJE OWO AIYE


Ao pa esinsin 9 , ao lo lenun ona pelu ose abuwe die , ao lo fi omi to loworo fo ori na
sinun kòtò.

(e) (OGUN EFORI TABI TULU)


EWE EJINRIN. ORI APARO. ODIDI ATARE. AOGUN PO KUNA
DADA.AOPOLOSE.AO MAFI FO ORI NI.

(f) AKO EFORI/TULU(Migrane)


Eyo oka baba9,eyo atare 9,a o gun papo mo ose dudu,ao su ewe ETIPONLA bi kainkain
a o fi ose yen si a o mafi fo gbogbo ori sinu ike kan a o da si orita.
(g) IWOSAN EFORI TOLE
EGUNGUN AGBARI AJA AO LO PELU OKO ATARE KAN AO TENI IFA EJIOBE
AO PE OHUN RESI AO FI SIN GBERE SIWAJU ORI NA
OHUN RE:- KIN,KIN ORUKO,TI ANPE ORI 3* AJA LORI ENIA LORI 3X ORI KI FO AJA 3X ESAN WA
3X ELAGARA 3X MAFI OWO LAMI LORI 3X IGI OLUFE TOLANU KI OPADE 3X KI ORI TONSAN
L,O,L,YI KI OFI SILE NI KIAKIA ODUMARE JOWO BAMI SEGUN EFORI O ODUMARE ASE O.
AO WA FI SIN GBERE SIWAJU ORINA.

(h) OGUN EFORI EYIKEYI TODAJU.


Ako koun, ao gun mo ose ao fi fo ori sinu ikekan ni ale a o lo da omi tia fori na si orita
meta pelu kankan rẹ.

(i) EFORI TULU


Ewe rinrin ti aba fe ja, ao je atare 9 fun okunrin, 7 fun obirin, ao wa sope a tojo aterun
tutu dodo lanba ewe rinrin ekan soso lao fatu ao gbon yepe idi re kuro ao lo loju olo ao
te ejiogbe si ao wa fi omi igbin fori na ao wa sin gbere 9 fun okunrin 7 fun obirin si arin
ori na.
(j) Ogun efori todaju,
Eku asinrin,ewe ajeobale ati odidi atare odidi kan,ao lo won papo,ao da sinu adi eyan,ao
ma fi pa ori lasan lalale.

(30) ẸDA (VIRGINAL DISCHARGE)

(a) AGUNMU EDA TODAJU:


EMO AGBO,EMO AJAO,ODINDI ATARE MARUN,AO GUN PAPO YIO MA FIMU
EKO.

(b) OGUN EDA PATAKI,


Ewe esisile, aolo aofise eja abori kanje fun obinrin naaaa.

(c) OGUN EDA.


A O LOWA IGO DUDU EYIKEYI, A O LO KUNA DADA PELU ODIDI ATARE KAN,
OKO ATI IYAWO NI YIO MAFI FO EKO TUTU MU.
(d) EDA
Ako kahun, alubosa elewe, atare Mewa, ESO ako, ao jo po, ao ma fi mu eko tutu.

(e) Egbo owo tutu, labelabe tutu, esu pupa, poroporo oka esa, ao fi omi se, ko bere si lo
ti obinrin na ba ti bere si ri nkan osu re di ojo karun.

(f) EDA IBULE TABI ORO


Egbo ajeobale, ewe bonni, obi meta, kanhun, atare meta, ewe patanma, ao gun po, eko
tutu lao ma fi mu..

(g) OGUN EDA OBINRIN TODAJU


AOWA AFOMO OGIRI AOFI ODIDI ATARE KAN JO AOLO AODA SINU IPARA
TI AFINDIRUN ALEDA SINU ADIAGBON KI OBINRIN NA FIDI IRUN RE
KOGBODO SUNMO OKUNRIN FUN OJO MARUN TOBADI OJO KEFA ISE BERE
EDA NA YIO SI Dúró.

(h) OGUN EDA TODAJU


AOLO ABEERE KUNO PELU ALUM DUDU AOWAFI OMI DIE SU RUGUDU
AOTIBO OJU ARA LALE Mojumo.

(h) OGUN EDA ARA OBINRIN


ESO IYALODE FF ELEYI TO GBE AO LA ESO YEN AO YO FUNFUN INURE YEN
AO LO KUNNA,AO WA OTI KAN AO WA OYIN IGAN AO DA OTI ATI OYIN PAPO
TIWON YO SE DEDE ARAWON AO WADA KINNI TIA LOYEN SINU RE AO MI
PAPO MINU FUN ENINA KODA ISEYI TUN NSISE FUN GBOGBO ARUN INU
KODA OWULO FUN AMBELORUN Pápá.

(i) OGUN EDA EYIKEYI:


Emo agbo lopolopo,emo ajao,odindi atare marun,a o gun gbogbo re papo ni
agunmu,obinrin yio maa fi mu eko tútù.

(j) OGUN EDA EYIKEYI TABI GBOGBONSE FUN ANBELOHUN:


A o yo gbogbo nkan inu abo adie to nye lowo ati obore sinu odo,odindi atare
meta,kanwun,osu pupa,eemo agbo,ebose adie naa,orogbo merin,obi merin,a o gun
gbogbo won ni ototo,a o sa gbe a o tun gun kunna,ao da papo obinrin yio maa fimu eko
gbigbona.

You might also like

pFad - Phonifier reborn

Pfad - The Proxy pFad of © 2024 Garber Painting. All rights reserved.

Note: This service is not intended for secure transactions such as banking, social media, email, or purchasing. Use at your own risk. We assume no liability whatsoever for broken pages.


Alternative Proxies:

Alternative Proxy

pFad Proxy

pFad v3 Proxy

pFad v4 Proxy