Ẹ̀tẹ̀
Ẹ̀tẹ̀ | |
---|---|
Arákunrin ọmọ ọdún 24 láti Norway, tí ó ní ẹ̀tẹ̀, 1886. | |
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta | |
ICD/CIM-10 | A30. A30. |
ICD/CIM-9 | 030 030 |
OMIM | 246300 |
DiseasesDB | 8478 |
MedlinePlus | 001347 |
Ẹ̀tẹ̀, tí a tún mọ̀sí Àrùn Hansen (HD), jẹ́́ bárakú àkóràn ti kòkòrò àrùn Mycobacterium leprae[1] àti Mycobacterium lepromatosis.Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid parameter in <ref>
tag Lákọkọ́, àwọn àkóràn kòní àwọn aamì wọ́n sì wà báyì fún ọdún 5 lọsí 20 ọdún.[1] Àwọn aamì tí o ń farahàn ni granuloma ti àwọn isan imọ̀, ibi atẹ́gùn ìmí ńgbà, àwọ̀ ara, àti àwọn ojú.[1] Èyí lè fa ìrora àti ìpàdánù àwọn ẹ̀yà ìkángun nítorí ìfarapa léraléra.[2] Àìlera àti àìríran dáradára lè wáyé.[2]
Orísi àwọn arùn dálé iye irúfẹ́ kòkòrò tí ó wà níbẹ̀: paucibacillary àti multibacillary.[2] Àwọn irúfẹ́ méjì yíì yàtọ̀ nípa iye àwọn ohun ayí àwọ̀ padà tí kò dára, àwọn bálabála àwọn ara, pẹ̀lú tí o ní márùn tàbí díẹ̀ àti multibacillary tí o ní ju márùn.[2] A sàwarí ìwádìí àìsàn yíì nípa wíwá acid-fast bacilli ní àyẹ̀wò ìsú-ara ti awọ̀ ara tàbí nípa ṣísàwarí DNA nípa polymerase àbájáde ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ̀létẹ̀lé.[2] Ó sábà maa ń ṣsẹlẹ̀ láàrin àwọn tí o ń gbé nínu òsì a sì gbàgbọ́ pé o maa ń ràn nípa àwọn mímí tí o ń wáyé.[2] O ní àrànmọ́ tí ó ga.[2]
A maa ń wo ẹ̀tẹ̀ sàn nípa ìtọjú.[1] Ìtọjú fún ẹ̀tẹ̀ paucibacillary ní àwọn egbògi dapsone àti rifampicin fún osù 6.[2] Ìtọjú fún ẹ̀tẹ̀ multibacillary ni rifampicin, dapsone, àti clofazimine fún osù méjìlá.[2] Àwọn ìtọjú yíì jẹ́ ọ̀fẹ́ láti ọwọ́ Àjọ Ìlera Àgbayé.[1] Ọ̀pọ̀ egbògi aṣòdìsí ni a tún lè lò.[2] Lágbayé ní 2012, iye ìṣẹlẹ̀ lílé ti ẹ̀tẹ̀ jẹ́ 189,000 àti iye ìṣẹlẹ̀ titun jẹ́ 230,000.[1] Iye ìṣẹlẹ̀ líle ti dínkù láti 5.2 mílíọ́nù ní àwọn ọdún 1980.[1][3][4] Ọ̀pọ̀ àwọn ìsẹlẹ̀ titun wáyé ní orílẹ̀-èdè 16, tí Índíánì sí jẹ̀ bíi ìdajì.[1][2] Ní àwọn 20 ọdún sẹ́yìn, 16 mílíọ́nù àwọn ènìyàn lágbayé ni o ti rí ìwosàn lọ́wọ ẹ̀tẹ̀.[1]
Ẹ̀tẹ̀ ti ń ran àwọn ènìyàn fún àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn.[2] Àrùn yí gba orúkọ rẹ láti Látínì ọ̀rọ̀ lepra, tí ó túnmọ̀ sí "scaly", nígbà tí ọ̀rọ̀ "Àrùn Hansen" wá láti orúkọ oníṣègùn Gerhard Armauer Hansen.[2] Yíya àwọn èniyàn sọ́tọ̀ ní awọn ìletò adẹ́tẹ̀ ṣsì ń wáyé ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Índíánì, pẹ̀lú iye ju ẹgbẹ̀gbẹ̀rún lọ;[5] Ṣáínà, pẹ̀lú iye ní ọgọgọ́rùn;[6] àti ní Áfíríkà.[7] Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ìletò kòsí mọ́.[7] Ẹ̀tẹ̀ ni ó rọ̀mọ́ àbùkù ìbálópọ̀ fún ọ̀pọ̀ ìtàn,[1] tí ó jẹ́ ìdènà fún ìfi-ara-ẹni sùn àti ìtọjú lọ́gán. Ọjọ́ Ẹ̀tẹ̀ Àgbayé bẹ̀rẹ̀ ní 1954 láti mú mímọ̀ nípa wá fún àwọn tí o ní ẹ̀tẹ̀.[8]
Awon ami ati ifarahan
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Awon ami ti o wopo ti a maa n ri fun eyikeyi arun ete ni bi imu to n se omi, ara gbigbe; arun oju; egbo ara, irewesi si isan; ara pipon; aini imolara ni ika owo ati ese.[9] Siwajusi, epon maa n kere si, ati pe, oko okunri le ma dide daradara.[10]
-
Egbo ara ni itan eni ti ete mu
-
Owo ti ete ti baje
Okunfa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]M. leprae and M. lepromatosis
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]M. leprae ati M. lepromatosis je mycobacteria ti o n se okunfa ete.[11] M. lepromatosis je mycobacteria ti a sese mo ti a si yo jade lati ara eni ti o ni diffuse lepromatous leprosy ni odun 2008.[12][13]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.00 1.01 1.02 1.03 1.04 1.05 1.06 1.07 1.08 1.09 "Leprosy Fact sheet N°101". World Health Organization. Jan 2014.
- ↑ 2.00 2.01 2.02 2.03 2.04 2.05 2.06 2.07 2.08 2.09 2.10 2.11 2.12 .
- ↑ .
- ↑ .
- ↑ "The hidden suffering of India's lepers ". BBC News . 2007-03-31.
- ↑ Lyn TE (2006-09-13 ). "Ignorance breeds leper colonies in China ". Independat News & Media . http://www.iol.co.za/index.php?set_id=1&click_id=117&art_id=qw1158139440409B243. Retrieved 2010-01-31.
- ↑ 7.0 7.1 Byrne, Joseph P. (2008). Encyclopedia of pestilence, pandemics, and plagues. Westport, Conn.[u.a.]: Greenwood Press. p. 351. ISBN 9780313341021. http://books.google.ca/books?id=5Pvi-ksuKFIC&pg=PA351.
- ↑ McMenamin, Dorothy (2011). Leprosy and stigma in the South Pacific : a region-by-region history with first person accounts. Jefferson, N.C.: McFarland. p. 17. ISBN 9780786463237. http://books.google.ca/books?id=lZPvQTJ8SE0C&pg=PA17.
- ↑ "Signs and Symptoms | Hansen's Disease (Leprosy) | CDC". www.cdc.gov. 2018-10-22. Retrieved 2019-07-22.
- ↑ admin (2016-02-11). "Pathogenesis and Pathology of Leprosy". International Textbook of Leprosy. Retrieved 2019-07-22.
- ↑ Reinar, Liv Merete; Forsetlund, Louise; Lehman, Linda Faye; Brurberg, Kjetil G (2021-06-02). "Interventions for ulceration and other skin changes caused by nerve damage in leprosy". The Cochrane Database of Systematic Reviews 2019 (7). doi:10.1002/14651858.CD012235.pub2. PMID 31425632. https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC6699662/. Retrieved 2022-02-21.
- ↑ "New Leprosy Bacterium: Scientists Use Genetic Fingerprint To Nail 'Killing Organism'". ScienceDaily. 2008-11-28. Archived from the original on 2010-03-13. Retrieved 2010-01-31. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Ryan, Kenneth J.; Ray, C. George, eds (2004). Sherris Medical Microbiology (4th ed.). McGraw Hill. pp. 451–53. ISBN 978-0-8385-8529-0. OCLC 61405904. https://archive.org/details/sherrismedicalmi00ryan.