Jump to content

Ẹ̀tẹ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ẹ̀tẹ̀
Ẹ̀tẹ̀Arákunrin ọmọ ọdún 24 láti Norway, tí ó ní ẹ̀tẹ̀, 1886.
Ẹ̀tẹ̀Arákunrin ọmọ ọdún 24 láti Norway, tí ó ní ẹ̀tẹ̀, 1886.
Arákunrin ọmọ ọdún 24 láti Norway, tí ó ní ẹ̀tẹ̀, 1886.
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10A30. A30.
ICD/CIM-9030 030
OMIM246300
DiseasesDB8478
MedlinePlus001347

Ẹ̀tẹ̀, tí a tún mọ̀sí Àrùn Hansen (HD), jẹ́́ bárakú àkóràn ti kòkòrò àrùn Mycobacterium leprae[1] àti Mycobacterium lepromatosis.Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid parameter in <ref> tag Lákọkọ́, àwọn àkóràn kòní àwọn aamì wọ́n sì wà báyì fún ọdún 5 lọsí 20 ọdún.[1] Àwọn aamì tí o ń farahàn ni granuloma ti àwọn isan imọ̀ibi atẹ́gùn ìmí ńgbà, àwọ̀ ara, àti àwọn ojú.[1] Èyí lè fa ìrora àti ìpàdánù àwọn ẹ̀yà ìkángun nítorí ìfarapa léraléra.[2] Àìlera àti àìríran dáradára lè wáyé.[2]

Orísi àwọn arùn dálé iye irúfẹ́ kòkòrò tí ó wà níbẹ̀: paucibacillary àti multibacillary.[2] Àwọn irúfẹ́ méjì yíì yàtọ̀ nípa iye àwọn ohun ayí àwọ̀ padà tí kò dára, àwọn bálabála àwọn ara, pẹ̀lú tí o ní márùn tàbí díẹ̀ àti multibacillary tí o ní ju márùn.[2] A sàwarí ìwádìí àìsàn yíì nípa wíwá acid-fast bacilli ní àyẹ̀wò ìsú-ara ti awọ̀ ara tàbí nípa ṣísàwarí DNA nípa polymerase àbájáde ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ̀létẹ̀lé.[2] Ó sábà maa ń ṣsẹlẹ̀ láàrin àwọn tí o ń gbé nínu òsì a sì gbàgbọ́ pé o maa ń ràn nípa àwọn mímí tí o ń wáyé.[2] O ní àrànmọ́ tí ó ga.[2]

A maa ń wo ẹ̀tẹ̀ sàn nípa ìtọjú.[1] Ìtọjú fún ẹ̀tẹ̀ paucibacillary ní àwọn egbògi dapsone àti rifampicin fún osù 6.[2] Ìtọjú fún ẹ̀tẹ̀ multibacillary ni rifampicindapsone, àti clofazimine fún osù méjìlá.[2] Àwọn ìtọjú yíì jẹ́ ọ̀fẹ́ láti ọwọ́ Àjọ Ìlera Àgbayé.[1] Ọ̀pọ̀ egbògi aṣòdìsí ni a tún lè lò.[2] Lágbayé ní 2012, iye ìṣẹlẹ̀ lílé ti ẹ̀tẹ̀ jẹ́ 189,000 àti iye ìṣẹlẹ̀ titun jẹ́ 230,000.[1] Iye ìṣẹlẹ̀ líle ti dínkù láti 5.2 mílíọ́nù ní àwọn ọdún 1980.[1][3][4] Ọ̀pọ̀ àwọn ìsẹlẹ̀ titun wáyé ní orílẹ̀-èdè 16, tí Índíánì sí jẹ̀ bíi ìdajì.[1][2] Ní àwọn 20 ọdún sẹ́yìn, 16 mílíọ́nù àwọn ènìyàn lágbayé ni o ti rí ìwosàn lọ́wọ ẹ̀tẹ̀.[1]

Ẹ̀tẹ̀ ti ń ran àwọn ènìyàn fún àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn.[2] Àrùn yí gba orúkọ rẹ láti Látínì ọ̀rọ̀ lepra, tí ó túnmọ̀ sí "scaly", nígbà tí ọ̀rọ̀ "Àrùn Hansen" wá láti orúkọ oníṣègùn Gerhard Armauer Hansen.[2] Yíya àwọn èniyàn sọ́tọ̀ ní awọn ìletò adẹ́tẹ̀ ṣsì ń wáyé ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Índíánì, pẹ̀lú iye ju ẹgbẹ̀gbẹ̀rún lọ;[5] Ṣáínà, pẹ̀lú iye ní ọgọgọ́rùn;[6] àti ní Áfíríkà.[7] Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ìletò kòsí mọ́.[7] Ẹ̀tẹ̀ ni ó rọ̀mọ́ àbùkù ìbálópọ̀ fún ọ̀pọ̀ ìtàn,[1] tí ó jẹ́ ìdènà fún ìfi-ara-ẹni sùn àti ìtọjú lọ́gán. Ọjọ́ Ẹ̀tẹ̀ Àgbayé bẹ̀rẹ̀ ní 1954 láti mú mímọ̀ nípa wá fún àwọn tí o ní ẹ̀tẹ̀.[8]

Awon ami ati ifarahan

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Awon ami ti o wopo ti a maa n ri fun eyikeyi arun ete ni bi imu to n se omi, ara gbigbe; arun oju; egbo ara, irewesi si isan; ara pipon; aini imolara ni ika owo ati ese.[9] Siwajusi, epon maa n kere si, ati pe, oko okunri le ma dide daradara.[10]

M. leprae and M. lepromatosis

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

M. leprae ati M. lepromatosis je mycobacteria ti o n se okunfa ete.[11] M. lepromatosis je mycobacteria ti a sese mo ti a si yo jade lati ara eni ti o ni diffuse lepromatous leprosy ni odun 2008.[12][13]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.00 1.01 1.02 1.03 1.04 1.05 1.06 1.07 1.08 1.09 "Leprosy Fact sheet N°101". World Health Organization. Jan 2014. 
  2. 2.00 2.01 2.02 2.03 2.04 2.05 2.06 2.07 2.08 2.09 2.10 2.11 2.12 . 
  3. . 
  4. . 
  5. "The hidden suffering of India's lepers ". BBC News . 2007-03-31. 
  6. Lyn TE  (2006-09-13 ). "Ignorance breeds leper colonies in China ". Independat News & Media . http://www.iol.co.za/index.php?set_id=1&click_id=117&art_id=qw1158139440409B243. Retrieved 2010-01-31. 
  7. 7.0 7.1 Byrne, Joseph P. (2008). Encyclopedia of pestilence, pandemics, and plagues. Westport, Conn.[u.a.]: Greenwood Press. p. 351. ISBN 9780313341021. http://books.google.ca/books?id=5Pvi-ksuKFIC&pg=PA351. 
  8. McMenamin, Dorothy (2011). Leprosy and stigma in the South Pacific : a region-by-region history with first person accounts. Jefferson, N.C.: McFarland. p. 17. ISBN 9780786463237. http://books.google.ca/books?id=lZPvQTJ8SE0C&pg=PA17. 
  9. "Signs and Symptoms | Hansen's Disease (Leprosy) | CDC". www.cdc.gov. 2018-10-22. Retrieved 2019-07-22. 
  10. admin (2016-02-11). "Pathogenesis and Pathology of Leprosy". International Textbook of Leprosy. Retrieved 2019-07-22. 
  11. Reinar, Liv Merete; Forsetlund, Louise; Lehman, Linda Faye; Brurberg, Kjetil G (2021-06-02). "Interventions for ulceration and other skin changes caused by nerve damage in leprosy". The Cochrane Database of Systematic Reviews 2019 (7). doi:10.1002/14651858.CD012235.pub2. PMID 31425632. https://www.ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC6699662/. Retrieved 2022-02-21. 
  12. "New Leprosy Bacterium: Scientists Use Genetic Fingerprint To Nail 'Killing Organism'". ScienceDaily. 2008-11-28. Archived from the original on 2010-03-13. Retrieved 2010-01-31.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  13. Ryan, Kenneth J.; Ray, C. George, eds (2004). Sherris Medical Microbiology (4th ed.). McGraw Hill. pp. 451–53. ISBN 978-0-8385-8529-0. OCLC 61405904. https://archive.org/details/sherrismedicalmi00ryan. 
pFad - Phonifier reborn

Pfad - The Proxy pFad of © 2024 Garber Painting. All rights reserved.

Note: This service is not intended for secure transactions such as banking, social media, email, or purchasing. Use at your own risk. We assume no liability whatsoever for broken pages.


Alternative Proxies:

Alternative Proxy

pFad Proxy

pFad v3 Proxy

pFad v4 Proxy